Surah Aal-E-Imran Translated in Yoruba
اللَّهُ لَا إِلَٰهَ إِلَّا هُوَ الْحَيُّ الْقَيُّومُ
Allahu, ko si olohun kan ti ijosin to si afi Oun, Alaaye, Alamojuuto-eda
نَزَّلَ عَلَيْكَ الْكِتَابَ بِالْحَقِّ مُصَدِّقًا لِمَا بَيْنَ يَدَيْهِ وَأَنْزَلَ التَّوْرَاةَ وَالْإِنْجِيلَ
O so Tira (al-Ƙur’an) kale fun o pelu ododo, ti o n fi ohun t’o je ododo rinle nipa eyi t’o wa siwaju re. O si so Taorah ati ’Injil kale
مِنْ قَبْلُ هُدًى لِلنَّاسِ وَأَنْزَلَ الْفُرْقَانَ ۗ إِنَّ الَّذِينَ كَفَرُوا بِآيَاتِ اللَّهِ لَهُمْ عَذَابٌ شَدِيدٌ ۗ وَاللَّهُ عَزِيزٌ ذُو انْتِقَامٍ
ni isaaju. Imona si ni fun awon eniyan.1 O tun so oro-ipinya (oro t’o n sepinya laaarin ododo ati iro) kale.2 Dajudaju awon t’o sai gbagbo ninu awon ayah Allahu, iya t’o le n be fun won. Allahu si ni Alagbara, Olugbesan
إِنَّ اللَّهَ لَا يَخْفَىٰ عَلَيْهِ شَيْءٌ فِي الْأَرْضِ وَلَا فِي السَّمَاءِ
Dajudaju Allahu, ko si kini kan t’o pamo fun Un ninu ile ati ninu sanmo
هُوَ الَّذِي يُصَوِّرُكُمْ فِي الْأَرْحَامِ كَيْفَ يَشَاءُ ۚ لَا إِلَٰهَ إِلَّا هُوَ الْعَزِيزُ الْحَكِيمُ
Oun ni Eni ti O n yaworan yin sinu apoluke bi O se fe. Ko si olohun kan ti ijosin to si afi Oun, Alagbara Ologbon
هُوَ الَّذِي أَنْزَلَ عَلَيْكَ الْكِتَابَ مِنْهُ آيَاتٌ مُحْكَمَاتٌ هُنَّ أُمُّ الْكِتَابِ وَأُخَرُ مُتَشَابِهَاتٌ ۖ فَأَمَّا الَّذِينَ فِي قُلُوبِهِمْ زَيْغٌ فَيَتَّبِعُونَ مَا تَشَابَهَ مِنْهُ ابْتِغَاءَ الْفِتْنَةِ وَابْتِغَاءَ تَأْوِيلِهِ ۗ وَمَا يَعْلَمُ تَأْوِيلَهُ إِلَّا اللَّهُ ۗ وَالرَّاسِخُونَ فِي الْعِلْمِ يَقُولُونَ آمَنَّا بِهِ كُلٌّ مِنْ عِنْدِ رَبِّنَا ۗ وَمَا يَذَّكَّرُ إِلَّا أُولُو الْأَلْبَابِ
Oun ni Eni ti O so Tira kale fun o; awon ayah alainipon-na wa ninu re - awon si ni ipile Tira -, onipon-na si ni iyoku. Ni ti awon ti igbunri kuro nibi ododo wa ninu okan won, won yoo maa tele eyi t’o ni pon-na ninu re lati fi wa wahala ati lati fi wa itumo (odi) fun un. Ko si si eni t’o nimo itumo re afi Allahu. Awon agba ninu imo esin, won n so pe: “A gba a gbo. Lati odo Oluwa wa ni gbogbo re (ti sokale).” Ko si eni t’o n lo iranti ayafi awon onilaakaye. ko si ayah tabi hadith kan ti o ni pon-na ti itakora won wa wo ipo “itakora toribee” (at-ta‘arudu al-haƙiƙiy). Eyi wa ni ibamu si surah an-Nisa’
رَبَّنَا لَا تُزِغْ قُلُوبَنَا بَعْدَ إِذْ هَدَيْتَنَا وَهَبْ لَنَا مِنْ لَدُنْكَ رَحْمَةً ۚ إِنَّكَ أَنْتَ الْوَهَّابُ
Oluwa wa, ma se yi wa lokan pada leyin ti O ti to wa sona. Ta wa lore ike lati odo Re, dajudaju Iwo ni Olore
رَبَّنَا إِنَّكَ جَامِعُ النَّاسِ لِيَوْمٍ لَا رَيْبَ فِيهِ ۚ إِنَّ اللَّهَ لَا يُخْلِفُ الْمِيعَادَ
Oluwa wa, dajudaju Iwo l’O maa ko awon eniyan jo ni ojo kan, ti ko si iyemeji ninu re. Dajudaju Allahu ki i ye adehun
إِنَّ الَّذِينَ كَفَرُوا لَنْ تُغْنِيَ عَنْهُمْ أَمْوَالُهُمْ وَلَا أَوْلَادُهُمْ مِنَ اللَّهِ شَيْئًا ۖ وَأُولَٰئِكَ هُمْ وَقُودُ النَّارِ
Dajudaju awon t’o sai gbagbo, awon dukia won ati awon omo won ko nii ro won loro kini kan lodo Allahu. Awon wonyen, awon ni nnkan ikona
Load More