Quran Apps in many lanuages:

Surah Al-Ahzab Translated in Yoruba

يَا أَيُّهَا النَّبِيُّ اتَّقِ اللَّهَ وَلَا تُطِعِ الْكَافِرِينَ وَالْمُنَافِقِينَ ۗ إِنَّ اللَّهَ كَانَ عَلِيمًا حَكِيمًا
Iwo Anabi, beru Allahu. Ma si tele awon alaigbagbo ati awon sobe-selu musulumi. Dajudaju Allahu n je Onimo, Ologbon
وَاتَّبِعْ مَا يُوحَىٰ إِلَيْكَ مِنْ رَبِّكَ ۚ إِنَّ اللَّهَ كَانَ بِمَا تَعْمَلُونَ خَبِيرًا
Tele ohun ti A n mu wa fun o ni imisi lati odo Oluwa re. Dajudaju Allahu n je Alamotan nipa ohun ti e n se nise
وَتَوَكَّلْ عَلَى اللَّهِ ۚ وَكَفَىٰ بِاللَّهِ وَكِيلًا
Ki o si gbarale Allahu. Allahu si to ni Oluso
مَا جَعَلَ اللَّهُ لِرَجُلٍ مِنْ قَلْبَيْنِ فِي جَوْفِهِ ۚ وَمَا جَعَلَ أَزْوَاجَكُمُ اللَّائِي تُظَاهِرُونَ مِنْهُنَّ أُمَّهَاتِكُمْ ۚ وَمَا جَعَلَ أَدْعِيَاءَكُمْ أَبْنَاءَكُمْ ۚ ذَٰلِكُمْ قَوْلُكُمْ بِأَفْوَاهِكُمْ ۖ وَاللَّهُ يَقُولُ الْحَقَّ وَهُوَ يَهْدِي السَّبِيلَ
Allahu ko fun eniyan kan ni okan meji ninu ikun re. (Allahu) ko si so awon iyawo yin, ti e n fi eyin won we eyin iya yin, di iya yin. Ati pe (Allahu) ko so awon omo-olomo ti e n pe ni omo yin di omo yin. Iyen ni oro enu yin. Allahu n so ododo. Ati pe Oun l’O n fi (eda) mona
ادْعُوهُمْ لِآبَائِهِمْ هُوَ أَقْسَطُ عِنْدَ اللَّهِ ۚ فَإِنْ لَمْ تَعْلَمُوا آبَاءَهُمْ فَإِخْوَانُكُمْ فِي الدِّينِ وَمَوَالِيكُمْ ۚ وَلَيْسَ عَلَيْكُمْ جُنَاحٌ فِيمَا أَخْطَأْتُمْ بِهِ وَلَٰكِنْ مَا تَعَمَّدَتْ قُلُوبُكُمْ ۚ وَكَانَ اللَّهُ غَفُورًا رَحِيمًا
E pe won pelu oruko baba won. Ohun l’o se deede julo lodo Allahu, sugbon ti e o ba mo (oruko) baba won, omo iya yin ninu esin ati eru yin kuku ni won. Ko si ese fun yin nipa ohun ti e ba sasise re, sugbon (ese wa nibi) ohun ti okan yin moomo se. Allahu si n je Alaforijin, Asake-orun
النَّبِيُّ أَوْلَىٰ بِالْمُؤْمِنِينَ مِنْ أَنْفُسِهِمْ ۖ وَأَزْوَاجُهُ أُمَّهَاتُهُمْ ۗ وَأُولُو الْأَرْحَامِ بَعْضُهُمْ أَوْلَىٰ بِبَعْضٍ فِي كِتَابِ اللَّهِ مِنَ الْمُؤْمِنِينَ وَالْمُهَاجِرِينَ إِلَّا أَنْ تَفْعَلُوا إِلَىٰ أَوْلِيَائِكُمْ مَعْرُوفًا ۚ كَانَ ذَٰلِكَ فِي الْكِتَابِ مَسْطُورًا
Anabi ni eto si awon onigbagbo ododo ju emi ara won lo (nipa ife re ati idajo re). Awon aya re si ni iya won. Ninu Tira Allahu, awon ebi, apa kan won ni eto si ogun jije ju apa kan lo. (Awon ebi tun ni eto si ogun jije) ju awon onigbagbo ododo ati awon t’o kuro ninu ilu Mokkah fun aabo esin, afi ti e ba maa se daadaa kan si awon ore yin (wonyi ni ogun le fi kan won pelu asoole). Iyen wa ninu Tira (Laohul-Mahfuth) ni akosile
وَإِذْ أَخَذْنَا مِنَ النَّبِيِّينَ مِيثَاقَهُمْ وَمِنْكَ وَمِنْ نُوحٍ وَإِبْرَاهِيمَ وَمُوسَىٰ وَعِيسَى ابْنِ مَرْيَمَ ۖ وَأَخَذْنَا مِنْهُمْ مِيثَاقًا غَلِيظًا
(Ranti) nigba ti A gba adehun ni owo awon Anabi ati ni owo re, ati ni owo (Anabi) Nuh, ’Ibrohim, Musa ati ‘Isa omo Moryam. A gba adehun ni owo won ni adehun t’o nipon
لِيَسْأَلَ الصَّادِقِينَ عَنْ صِدْقِهِمْ ۚ وَأَعَدَّ لِلْكَافِرِينَ عَذَابًا أَلِيمًا
nitori ki (Allahu) le beere (ododo) awon olododo nipa ododo won. O si pese iya eleta-elero sile de awon alaigbagbo
يَا أَيُّهَا الَّذِينَ آمَنُوا اذْكُرُوا نِعْمَةَ اللَّهِ عَلَيْكُمْ إِذْ جَاءَتْكُمْ جُنُودٌ فَأَرْسَلْنَا عَلَيْهِمْ رِيحًا وَجُنُودًا لَمْ تَرَوْهَا ۚ وَكَانَ اللَّهُ بِمَا تَعْمَلُونَ بَصِيرًا
Eyin ti e gbagbo ni ododo, e ranti idera Allahu lori yin, nigba ti awon omo ogun (onijo) de ba yin. A si ran ategun ati awon omo ogun ti e o foju ri si won. Allahu si ni Oluriran nipa ohun ti e n se
إِذْ جَاءُوكُمْ مِنْ فَوْقِكُمْ وَمِنْ أَسْفَلَ مِنْكُمْ وَإِذْ زَاغَتِ الْأَبْصَارُ وَبَلَغَتِ الْقُلُوبُ الْحَنَاجِرَ وَتَظُنُّونَ بِاللَّهِ الظُّنُونَا
(E ranti) nigba ti won de ba yin lati oke yin ati isale yin, ati nigba ti awon oju ye (sotun-un sosi), ti awon okan si de ona-ofun (ni ti ipaya). E si n ro awon ero kan nipa Allahu
Load More