Surah Al-Anaam Translated in Yoruba
الْحَمْدُ لِلَّهِ الَّذِي خَلَقَ السَّمَاوَاتِ وَالْأَرْضَ وَجَعَلَ الظُّلُمَاتِ وَالنُّورَ ۖ ثُمَّ الَّذِينَ كَفَرُوا بِرَبِّهِمْ يَعْدِلُونَ
Gbogbo ope n je ti Allahu, Eni ti O da awon sanmo ati ile. O tun da okunkun ati imole. Sibesibe awon t’o sai gbagbo n ba Oluwa won wa akegbe
هُوَ الَّذِي خَلَقَكُمْ مِنْ طِينٍ ثُمَّ قَضَىٰ أَجَلًا ۖ وَأَجَلٌ مُسَمًّى عِنْدَهُ ۖ ثُمَّ أَنْتُمْ تَمْتَرُونَ
Oun ni Eni ti O da yin lati inu erupe amo. Leyin naa, O fi gbedeke igba kan si (isemi aye yin). Ati pe gbedeke akoko kan (tun wa fun aye) lodo Re. Leyin naa, e tun n seyemeji
وَهُوَ اللَّهُ فِي السَّمَاوَاتِ وَفِي الْأَرْضِ ۖ يَعْلَمُ سِرَّكُمْ وَجَهْرَكُمْ وَيَعْلَمُ مَا تَكْسِبُونَ
Oun ni Allahu ninu awon sanmo ati ninu ile. O mo ikoko yin ati gbangba yin. O si mo ohun ti e n se nise
وَمَا تَأْتِيهِمْ مِنْ آيَةٍ مِنْ آيَاتِ رَبِّهِمْ إِلَّا كَانُوا عَنْهَا مُعْرِضِينَ
Ko si ami kan ti o maa de ba won ninu awon ami Oluwa won, afi ki won maa gbunri kuro nibe
فَقَدْ كَذَّبُوا بِالْحَقِّ لَمَّا جَاءَهُمْ ۖ فَسَوْفَ يَأْتِيهِمْ أَنْبَاءُ مَا كَانُوا بِهِ يَسْتَهْزِئُونَ
Won kuku pe ododo niro nigba ti o de ba won. Nitori naa, laipe awon iro ohun ti won maa n fi se yeye n bo wa ba won
أَلَمْ يَرَوْا كَمْ أَهْلَكْنَا مِنْ قَبْلِهِمْ مِنْ قَرْنٍ مَكَّنَّاهُمْ فِي الْأَرْضِ مَا لَمْ نُمَكِّنْ لَكُمْ وَأَرْسَلْنَا السَّمَاءَ عَلَيْهِمْ مِدْرَارًا وَجَعَلْنَا الْأَنْهَارَ تَجْرِي مِنْ تَحْتِهِمْ فَأَهْلَكْنَاهُمْ بِذُنُوبِهِمْ وَأَنْشَأْنَا مِنْ بَعْدِهِمْ قَرْنًا آخَرِينَ
Se won ko ri i pe meloo meloo ninu awon iran ti A ti pare siwaju won? Awon ti A fun ni ipo lori ile, (iru) ipo ti A ko fun eyin. A si ro omi ojo pupo fun won lati sanmo. A si se awon odo ti n san si isale (ile) won. Leyin naa, A pa won re nitori ese won. A si da awon iran miiran leyin won
وَلَوْ نَزَّلْنَا عَلَيْكَ كِتَابًا فِي قِرْطَاسٍ فَلَمَسُوهُ بِأَيْدِيهِمْ لَقَالَ الَّذِينَ كَفَرُوا إِنْ هَٰذَا إِلَّا سِحْرٌ مُبِينٌ
Ti o ba je pe A so tira kan ti A ko sinu takada kale fun o, ki won si fi owo won gba a mu (bayii), dajudaju awon t’o sai gbagbo iba wi pe: “Ki ni eyi bi ko se idan ponnbele.”
وَقَالُوا لَوْلَا أُنْزِلَ عَلَيْهِ مَلَكٌ ۖ وَلَوْ أَنْزَلْنَا مَلَكًا لَقُضِيَ الْأَمْرُ ثُمَّ لَا يُنْظَرُونَ
Won si wi pe: “Nitori ki ni Won ko se so molaika kan kale fun un?” Ti o ba je pe A so molaika kan kale, oro iba ti yanju. Leyin naa, A o si nii lo won lara mo
وَلَوْ جَعَلْنَاهُ مَلَكًا لَجَعَلْنَاهُ رَجُلًا وَلَلَبَسْنَا عَلَيْهِمْ مَا يَلْبِسُونَ
Ti o ba je pe A se e ni molaika ni, Awa iba se e ni okunrin. Ati pe Awa iba tun fi ohun ti won n daru mora won loju ru won loju
وَلَقَدِ اسْتُهْزِئَ بِرُسُلٍ مِنْ قَبْلِكَ فَحَاقَ بِالَّذِينَ سَخِرُوا مِنْهُمْ مَا كَانُوا بِهِ يَسْتَهْزِئُونَ
Won kuku ti fi awon Ojise kan se yeye siwaju re! Nitori naa, ohun ti won n fi se yeye si diya t’o yi awon t’o n fi won se yeye po
Load More