Surah Al-Anbiya Translated in Yoruba
اقْتَرَبَ لِلنَّاسِ حِسَابُهُمْ وَهُمْ فِي غَفْلَةٍ مُعْرِضُونَ
Isiro-ise sunmo fun awon eniyan, won si wa ninu ifonufora, ti won n gbunri (kuro nibi ododo)
مَا يَأْتِيهِمْ مِنْ ذِكْرٍ مِنْ رَبِّهِمْ مُحْدَثٍ إِلَّا اسْتَمَعُوهُ وَهُمْ يَلْعَبُونَ
Ko si iranti titun kan ti o maa de ba won lati odo Oluwa won afi ki won gbo o pelu ere sise
لَاهِيَةً قُلُوبُهُمْ ۗ وَأَسَرُّوا النَّجْوَى الَّذِينَ ظَلَمُوا هَلْ هَٰذَا إِلَّا بَشَرٌ مِثْلُكُمْ ۖ أَفَتَأْتُونَ السِّحْرَ وَأَنْتُمْ تُبْصِرُونَ
Won fonufora ni. Awon t’o sabosi si fi oro ikoko (aarin ara won) pamo pe: "Se eyi tayo abara bi iru yin ni? Se e maa tele idan ni, nigba ti eyin naa riran
قَالَ رَبِّي يَعْلَمُ الْقَوْلَ فِي السَّمَاءِ وَالْأَرْضِ ۖ وَهُوَ السَّمِيعُ الْعَلِيمُ
O so pe: “Oluwa mi mo oro t’o n be ninu sanmo ati ile. Oun ni Olugbo, Onimo.”
بَلْ قَالُوا أَضْغَاثُ أَحْلَامٍ بَلِ افْتَرَاهُ بَلْ هُوَ شَاعِرٌ فَلْيَأْتِنَا بِآيَةٍ كَمَا أُرْسِلَ الْأَوَّلُونَ
Rara, won tun wi pe: “Awon ala ti itumo re lopo mora won ni (al-Ƙur’an.” Won tun wi pe): “Rara, o hun un ni.” (Won tun wi pe): “Rara, elewi ni. Bi bee ko ki o mu ami kan wa fun wa gege bi won se fi ran awon eni akoko.”
مَا آمَنَتْ قَبْلَهُمْ مِنْ قَرْيَةٍ أَهْلَكْنَاهَا ۖ أَفَهُمْ يُؤْمِنُونَ
Ko si awon t’o gbagbo siwaju won ninu awon ilu ti A ti pare (leyin isokale ami). Se awon si maa gbagbo (nigba ti ami ba de)
وَمَا أَرْسَلْنَا قَبْلَكَ إِلَّا رِجَالًا نُوحِي إِلَيْهِمْ ۖ فَاسْأَلُوا أَهْلَ الذِّكْرِ إِنْ كُنْتُمْ لَا تَعْلَمُونَ
A o ran eni kan ni ise-ojise siwaju re afi awon okunrin ti A n fi imisi ranse si. Nitori naa, e beere lodo awon oniran-anti ti eyin ko ba mo
وَمَا جَعَلْنَاهُمْ جَسَدًا لَا يَأْكُلُونَ الطَّعَامَ وَمَا كَانُوا خَالِدِينَ
A ko si se won ni abara ti ko nii jeun. Won ko si je olusegbere (nile aye). abara ni ki i se olohun. Allahu awon oku ko le gbo oro kan kan mo lati odo awon alaaye ni ibamu si surah an-Naml; 27:80 surah ar-Rum; 30:52 ati surah Fatir; 35:22. Anabi wa Muhammad (sollalahu alayhi wa sallam) si pada di oku ti won bo mo inu saree ninu ilu Modinah Onimoole ni ibamu si surah az-Zumor; 39:30. Ko si si ayah taara kan ninu al-Ƙur’an ti o yo Anabi wa Muhammad (sollalahu alayhi wa sallam) sile ninu awon oku ti ko le gbo oro kan kan mo lati odo awon alaaye. Amo hadith t’o fese rinle wa ti o n fi rinle pe “Ko si eni kan ti o maa salamo si mi afi ki Allahu da emi mi pada si mi lara titi mo maa fi da salamo naa pada fun un.” Abu Daud l’o gba a wa labe akole: bab ziyaratul-ƙubur. Seek al-Baniy so pe “hadith naa dara”. Hadith yii tun wa ninu musnad ’Ahmad ati sunan Baehaƙiy. Ojise Allahu (sollalahu alayhi wa sallam) so pe “Dajudaju ojo Jum‘ah wa ninu awon ojo yin t’o loore julo; Won seda Anabi Adam (’alaehi-ssolatu wa-ssalam) ninu re ni isele t’o tayo oye wa amo ti o tenu Anabi wa Muhammad olododo (sollalahu alayhi wa sallam) jade ti o si dari yin pelu ohun ti n be lodo yin.” Eni kan ninu awon t’o gba hadith yii wa so pe “Ki ni itumo “ti o si dari yin pelu ohun ti n be lodo yin”? Tabi ki ni itumo “ti ohun ti o maa fi dari yin si maa wa lati odo yin?” Ibnu Abi Thanb si fesi pe
ثُمَّ صَدَقْنَاهُمُ الْوَعْدَ فَأَنْجَيْنَاهُمْ وَمَنْ نَشَاءُ وَأَهْلَكْنَا الْمُسْرِفِينَ
Leyin naa, A mu adehun Wa se fun won. A si gba awon Ojise ati awon ti A ba fe la. A si pa awon olutayo enu-ala run
لَقَدْ أَنْزَلْنَا إِلَيْكُمْ كِتَابًا فِيهِ ذِكْرُكُمْ ۖ أَفَلَا تَعْقِلُونَ
Dajudaju A ti so tira kan kale fun yin, ti iranti nipa oro ara yin wa ninu re. Nitori naa, se e o se laakaye ni
Load More