Surah Al-Anfal Translated in Yoruba
يَسْأَلُونَكَ عَنِ الْأَنْفَالِ ۖ قُلِ الْأَنْفَالُ لِلَّهِ وَالرَّسُولِ ۖ فَاتَّقُوا اللَّهَ وَأَصْلِحُوا ذَاتَ بَيْنِكُمْ ۖ وَأَطِيعُوا اللَّهَ وَرَسُولَهُ إِنْ كُنْتُمْ مُؤْمِنِينَ
Won n bi o leere nipa oro ogun. So pe: “Oro ogun je ti Allahu ati ti Ojise. Nitori naa, e beru Allahu. Ki e si se atunse nnkan ti n be laaarin yin. E tele ti Allahu ati Ojise Re ti e ba je onigbagbo ododo
إِنَّمَا الْمُؤْمِنُونَ الَّذِينَ إِذَا ذُكِرَ اللَّهُ وَجِلَتْ قُلُوبُهُمْ وَإِذَا تُلِيَتْ عَلَيْهِمْ آيَاتُهُ زَادَتْهُمْ إِيمَانًا وَعَلَىٰ رَبِّهِمْ يَتَوَكَّلُونَ
Awon onigbagbo ododo ni awon t’o je pe nigba ti won ba fi (iya) Allahu se iranti (fun won), okan won yoo wariri, nigba ti won ba si ke awon ayah Re fun won, won yoo lekun ni igbagbo ododo. Oluwa won si ni won n gbarale
الَّذِينَ يُقِيمُونَ الصَّلَاةَ وَمِمَّا رَزَقْنَاهُمْ يُنْفِقُونَ
(Awon ni) awon t’o n kirun, ti won si n na ninu ohun ti A pese fun won
أُولَٰئِكَ هُمُ الْمُؤْمِنُونَ حَقًّا ۚ لَهُمْ دَرَجَاتٌ عِنْدَ رَبِّهِمْ وَمَغْفِرَةٌ وَرِزْقٌ كَرِيمٌ
Ni ododo, awon wonyen ni onigbagbo ododo. Awon ipo giga, aforijin ati arisiki alapon-onle n be fun won lodo Oluwa won
كَمَا أَخْرَجَكَ رَبُّكَ مِنْ بَيْتِكَ بِالْحَقِّ وَإِنَّ فَرِيقًا مِنَ الْمُؤْمِنِينَ لَكَارِهُونَ
Gege bi Oluwa re se mu o jade (lo si oju ogun) lati inu ile re pelu ododo, dajudaju igun kan ninu awon onigbagbo ni emi won ko o
يُجَادِلُونَكَ فِي الْحَقِّ بَعْدَمَا تَبَيَّنَ كَأَنَّمَا يُسَاقُونَ إِلَى الْمَوْتِ وَهُمْ يَنْظُرُونَ
Won si n tako o nibi ododo leyin ti o ti foju han (si won) afi bi eni pe won n wa won lo si odo iku, ti won si n wo o (bayii)
وَإِذْ يَعِدُكُمُ اللَّهُ إِحْدَى الطَّائِفَتَيْنِ أَنَّهَا لَكُمْ وَتَوَدُّونَ أَنَّ غَيْرَ ذَاتِ الشَّوْكَةِ تَكُونُ لَكُمْ وَيُرِيدُ اللَّهُ أَنْ يُحِقَّ الْحَقَّ بِكَلِمَاتِهِ وَيَقْطَعَ دَابِرَ الْكَافِرِينَ
(Ranti) nigba ti Allahu sadehun okan ninu awon ijo mejeeji fun yin pe o maa je tiyin, eyin si n fe ki ijo ti ko dira ogun je tiyin. Allahu si fe mu ododo se pelu awon oro Re, O si (fe) pa awon alaigbagbo run patapata
لِيُحِقَّ الْحَقَّ وَيُبْطِلَ الْبَاطِلَ وَلَوْ كَرِهَ الْمُجْرِمُونَ
nitori ki (Allahu) le fi ododo (’Islam) rinle ni ododo, ki O si le pana iro (iborisa), awon elese (osebo) ibaa korira re
إِذْ تَسْتَغِيثُونَ رَبَّكُمْ فَاسْتَجَابَ لَكُمْ أَنِّي مُمِدُّكُمْ بِأَلْفٍ مِنَ الْمَلَائِكَةِ مُرْدِفِينَ
(Ranti) nigba ti e n wa iranlowo Oluwa yin, O si da yin lohun pe dajudaju Emi yoo ran yin lowo pelu egberun kan ninu awon molaika t’o maa wa ni telentele
وَمَا جَعَلَهُ اللَّهُ إِلَّا بُشْرَىٰ وَلِتَطْمَئِنَّ بِهِ قُلُوبُكُمْ ۚ وَمَا النَّصْرُ إِلَّا مِنْ عِنْدِ اللَّهِ ۚ إِنَّ اللَّهَ عَزِيزٌ حَكِيمٌ
Allahu ko si se (iranlowo awon molaika) lasan bi ko se nitori ki o le je iro idunnu ati nitori ki okan yin le bale pelu re. Ko si aranse kan afi lati odo Allahu. Dajudaju Allahu ni Alagbara, Ologbon
Load More