Quran Apps in many lanuages:

Surah Al-Ankabut Translated in Yoruba

الم
’Alif lam mim
أَحَسِبَ النَّاسُ أَنْ يُتْرَكُوا أَنْ يَقُولُوا آمَنَّا وَهُمْ لَا يُفْتَنُونَ
Nje awon eniyan lero pe A oo fi won sile ki won maa so pe: “A gbagbo”, ti A o si nii dan won wo
وَلَقَدْ فَتَنَّا الَّذِينَ مِنْ قَبْلِهِمْ ۖ فَلَيَعْلَمَنَّ اللَّهُ الَّذِينَ صَدَقُوا وَلَيَعْلَمَنَّ الْكَاذِبِينَ
A kuku ti dan awon t’o siwaju won wo. Nitori naa, dajudaju Allahu maa safi han awon t’o so ododo. Dajudaju O si maa safi han awon opuro
أَمْ حَسِبَ الَّذِينَ يَعْمَلُونَ السَّيِّئَاتِ أَنْ يَسْبِقُونَا ۚ سَاءَ مَا يَحْكُمُونَ
Abi awon t’o n se ise aburu lero pe awon maa mori bo mo Wa lowo ni? Ohun ti won n da lejo buru
مَنْ كَانَ يَرْجُو لِقَاءَ اللَّهِ فَإِنَّ أَجَلَ اللَّهِ لَآتٍ ۚ وَهُوَ السَّمِيعُ الْعَلِيمُ
Enikeni ti o ba n reti ipade Allahu, dajudaju akoko Allahu kuku n bo. Oun si ni Olugbo, Onimo
وَمَنْ جَاهَدَ فَإِنَّمَا يُجَاهِدُ لِنَفْسِهِ ۚ إِنَّ اللَّهَ لَغَنِيٌّ عَنِ الْعَالَمِينَ
Enikeni ti o ba gbiyanju, o n gbiyanju fun emi ara re ni. Dajudaju Allahu ni Oloro ti ko bukata si gbogbo eda
وَالَّذِينَ آمَنُوا وَعَمِلُوا الصَّالِحَاتِ لَنُكَفِّرَنَّ عَنْهُمْ سَيِّئَاتِهِمْ وَلَنَجْزِيَنَّهُمْ أَحْسَنَ الَّذِي كَانُوا يَعْمَلُونَ
Awon t’o ba gbagbo ni ododo, ti won si se ise rere, dajudaju A maa ha awon ise aburu won danu fun won. Dajudaju A o si san won lesan pelu eyi t’o dara ju ohun ti won n se
وَوَصَّيْنَا الْإِنْسَانَ بِوَالِدَيْهِ حُسْنًا ۖ وَإِنْ جَاهَدَاكَ لِتُشْرِكَ بِي مَا لَيْسَ لَكَ بِهِ عِلْمٌ فَلَا تُطِعْهُمَا ۚ إِلَيَّ مَرْجِعُكُمْ فَأُنَبِّئُكُمْ بِمَا كُنْتُمْ تَعْمَلُونَ
A pa a ni ase fun eniyan lati se daadaa si awon obi re mejeeji. Ti awon mejeeji ba si ja o logun pe ki o fi ohun ti iwo ko ni imo nipa re sebo si Mi, ma se tele awon mejeeji. Odo Mi ni ibupadasi yin. Nitori naa, Mo maa fun yin ni iro ohun ti e n se nise
وَالَّذِينَ آمَنُوا وَعَمِلُوا الصَّالِحَاتِ لَنُدْخِلَنَّهُمْ فِي الصَّالِحِينَ
Awon t’o ba gbagbo ni ododo, ti won si se ise rere, dajudaju A maa fi won sinu awon eni rere
وَمِنَ النَّاسِ مَنْ يَقُولُ آمَنَّا بِاللَّهِ فَإِذَا أُوذِيَ فِي اللَّهِ جَعَلَ فِتْنَةَ النَّاسِ كَعَذَابِ اللَّهِ وَلَئِنْ جَاءَ نَصْرٌ مِنْ رَبِّكَ لَيَقُولُنَّ إِنَّا كُنَّا مَعَكُمْ ۚ أَوَلَيْسَ اللَّهُ بِأَعْلَمَ بِمَا فِي صُدُورِ الْعَالَمِينَ
O n be ninu awon eniyan, eni t’o n wi pe: “A gba Allahu gbo.” Nigba ti won ba si fi inira kan won ninu esin Allahu, o maa so inira eniyan da bi iya ti Allahu. Ti aranse kan lati odo Oluwa re ba si de, dajudaju won yoo wi pe: “Dajudaju awa wa pelu yin.” Se Allahu ko l’O nimo julo nipa ohun ti n be ninu igba-aya gbogbo eda ni
Load More