Surah Al-Baqara Translated in Yoruba
ذَٰلِكَ الْكِتَابُ لَا رَيْبَ ۛ فِيهِ ۛ هُدًى لِلْمُتَّقِينَ
Eyi ni Tira naa, ti ko si iyemeji ninu re. Imona ni fun awon oluberu (Allahu)
الَّذِينَ يُؤْمِنُونَ بِالْغَيْبِ وَيُقِيمُونَ الصَّلَاةَ وَمِمَّا رَزَقْنَاهُمْ يُنْفِقُونَ
awon t’o gbagbo ninu (iro) ikoko, ti won n kirun, ti won si n na ninu ohun ti A pese fun won
وَالَّذِينَ يُؤْمِنُونَ بِمَا أُنْزِلَ إِلَيْكَ وَمَا أُنْزِلَ مِنْ قَبْلِكَ وَبِالْآخِرَةِ هُمْ يُوقِنُونَ
ati awon t’o gbagbo ninu ohun ti A sokale fun o ati ohun ti A sokale siwaju re, ti won si ni amodaju nipa Ojo Ikeyin
أُولَٰئِكَ عَلَىٰ هُدًى مِنْ رَبِّهِمْ ۖ وَأُولَٰئِكَ هُمُ الْمُفْلِحُونَ
Awon wonyen wa lori imona lati odo Oluwa won. Awon wonyen, awon ni olujere
إِنَّ الَّذِينَ كَفَرُوا سَوَاءٌ عَلَيْهِمْ أَأَنْذَرْتَهُمْ أَمْ لَمْ تُنْذِرْهُمْ لَا يُؤْمِنُونَ
Dajudaju awon t’o sai gbagbo, bakan naa ni fun won, yala o kilo fun won tabi o o kilo fun won, won ko nii gbagbo
خَتَمَ اللَّهُ عَلَىٰ قُلُوبِهِمْ وَعَلَىٰ سَمْعِهِمْ ۖ وَعَلَىٰ أَبْصَارِهِمْ غِشَاوَةٌ ۖ وَلَهُمْ عَذَابٌ عَظِيمٌ
Allahu fi edidi di okan won ati igboro won. Ebibo si bo iriran won. Iya nla si wa fun won
وَمِنَ النَّاسِ مَنْ يَقُولُ آمَنَّا بِاللَّهِ وَبِالْيَوْمِ الْآخِرِ وَمَا هُمْ بِمُؤْمِنِينَ
O si n be ninu awon eniyan, eni t’o n wi pe: “A gbagbo ninu Allahu ati Ojo Ikeyin.” Won ki i si se onigbagbo ododo
يُخَادِعُونَ اللَّهَ وَالَّذِينَ آمَنُوا وَمَا يَخْدَعُونَ إِلَّا أَنْفُسَهُمْ وَمَا يَشْعُرُونَ
Won n tan Allahu ati awon t’o gbagbo ni ododo je. Won ko si le tan eni kan je bi ko se emi ara won; won ko si fura
فِي قُلُوبِهِمْ مَرَضٌ فَزَادَهُمُ اللَّهُ مَرَضًا ۖ وَلَهُمْ عَذَابٌ أَلِيمٌ بِمَا كَانُوا يَكْذِبُونَ
Arun kan wa ninu okan won, nitori naa Allahu se alekun arun fun won. Iya eleta-elero si wa fun won nitori pe won n paro
Load More