Quran Apps in many lanuages:

Surah Al-Baqara Ayahs #202 Translated in Yoruba

لَيْسَ عَلَيْكُمْ جُنَاحٌ أَنْ تَبْتَغُوا فَضْلًا مِنْ رَبِّكُمْ ۚ فَإِذَا أَفَضْتُمْ مِنْ عَرَفَاتٍ فَاذْكُرُوا اللَّهَ عِنْدَ الْمَشْعَرِ الْحَرَامِ ۖ وَاذْكُرُوهُ كَمَا هَدَاكُمْ وَإِنْ كُنْتُمْ مِنْ قَبْلِهِ لَمِنَ الضَّالِّينَ
Ko si ibawi fun yin (nibi owo sise l’asiko ise hajj) pe ki e wa oore kan lati odo Oluwa yin. Nitori naa, ti e ba n dari bo lati ‘Arafah, e se iranti Allahu ni aye alapon-onle (Muzdalifah). E se iranti Re gege bi O se fi ona mo yin, bi o tile je pe teletele e wa ninu awon olusina
ثُمَّ أَفِيضُوا مِنْ حَيْثُ أَفَاضَ النَّاسُ وَاسْتَغْفِرُوا اللَّهَ ۚ إِنَّ اللَّهَ غَفُورٌ رَحِيمٌ
Leyin naa, e da lo si ibi ti awon eniyan ba da lo (ninu ise Hajj), ki e si toro aforijin Allahu. Dajudaju, Allahu ni Alaforijin, Asake-orun
فَإِذَا قَضَيْتُمْ مَنَاسِكَكُمْ فَاذْكُرُوا اللَّهَ كَذِكْرِكُمْ آبَاءَكُمْ أَوْ أَشَدَّ ذِكْرًا ۗ فَمِنَ النَّاسِ مَنْ يَقُولُ رَبَّنَا آتِنَا فِي الدُّنْيَا وَمَا لَهُ فِي الْآخِرَةِ مِنْ خَلَاقٍ
Nigba ti e ba pari ijosin (Hajj) yin, e seranti Allahu gege bi e se n seranti awon baba nla yin. Tabi ki iranti naa lagbara ju bee lo. Nitori naa, o n be ninu awon eniyan, eni t’o n wi pe: “Oluwa wa, fun wa ni oore aye.” Ko si nii si ipin oore kan fun un ni orun
وَمِنْهُمْ مَنْ يَقُولُ رَبَّنَا آتِنَا فِي الدُّنْيَا حَسَنَةً وَفِي الْآخِرَةِ حَسَنَةً وَقِنَا عَذَابَ النَّارِ
O si n be ninu won, eni t’o n so pe: "Oluwa wa, fun wa ni oore ni aye ati oore ni orun, ki O si so wa nibi iya Ina
أُولَٰئِكَ لَهُمْ نَصِيبٌ مِمَّا كَسَبُوا ۚ وَاللَّهُ سَرِيعُ الْحِسَابِ
Awon wonyen, tiwon ni ipin oore nipa ohun ti won se nise. Allahu si ni Oluyara nibi isiro-ise

Choose other languages: