Quran Apps in many lanuages:

Surah Al-Baqara Ayahs #83 Translated in Yoruba

فَوَيْلٌ لِلَّذِينَ يَكْتُبُونَ الْكِتَابَ بِأَيْدِيهِمْ ثُمَّ يَقُولُونَ هَٰذَا مِنْ عِنْدِ اللَّهِ لِيَشْتَرُوا بِهِ ثَمَنًا قَلِيلًا ۖ فَوَيْلٌ لَهُمْ مِمَّا كَتَبَتْ أَيْدِيهِمْ وَوَيْلٌ لَهُمْ مِمَّا يَكْسِبُونَ
Nitori naa, egbe ni fun awon t’o n fi owo ara won ko Tira, leyin naa ti won n wi pe: “Eyi wa lati odo Allahu.” Nitori ki won le ta a ni owo pooku. Egbe ni fun won se nipa ohun ti owo won ko. Egbe si ni fun won pelu nipa ohun ti won n se nise
وَقَالُوا لَنْ تَمَسَّنَا النَّارُ إِلَّا أَيَّامًا مَعْدُودَةً ۚ قُلْ أَتَّخَذْتُمْ عِنْدَ اللَّهِ عَهْدًا فَلَنْ يُخْلِفَ اللَّهُ عَهْدَهُ ۖ أَمْ تَقُولُونَ عَلَى اللَّهِ مَا لَا تَعْلَمُونَ
Won si wi pe: “Ina ko le fowo ba wa tayo ojo t’o lonka.” So pe: “Se e ti ri adehun kan gba lodo Allahu ni?”Allahu ko si nii yapa adehun Re. Se e fe safiti ohun ti e o nimo nipa re sodo Allahu ni
بَلَىٰ مَنْ كَسَبَ سَيِّئَةً وَأَحَاطَتْ بِهِ خَطِيئَتُهُ فَأُولَٰئِكَ أَصْحَابُ النَّارِ ۖ هُمْ فِيهَا خَالِدُونَ
Rara (Ina ko ri bi won se ro o si); enikeni ti o ba se ise ibi kan, ti awon ese re tun yi i ka, awon wonyen ni ero inu Ina. Olusegbere ni won ninu re
وَالَّذِينَ آمَنُوا وَعَمِلُوا الصَّالِحَاتِ أُولَٰئِكَ أَصْحَابُ الْجَنَّةِ ۖ هُمْ فِيهَا خَالِدُونَ
Awon t’o gbagbo ni ododo, ti won si se awon ise rere, awon wonyen ni ero inu Ogba Idera. Olusegbere ni won ninu re
وَإِذْ أَخَذْنَا مِيثَاقَ بَنِي إِسْرَائِيلَ لَا تَعْبُدُونَ إِلَّا اللَّهَ وَبِالْوَالِدَيْنِ إِحْسَانًا وَذِي الْقُرْبَىٰ وَالْيَتَامَىٰ وَالْمَسَاكِينِ وَقُولُوا لِلنَّاسِ حُسْنًا وَأَقِيمُوا الصَّلَاةَ وَآتُوا الزَّكَاةَ ثُمَّ تَوَلَّيْتُمْ إِلَّا قَلِيلًا مِنْكُمْ وَأَنْتُمْ مُعْرِضُونَ
(E ranti) nigba ti A gba adehun lowo awon omo ‘Isro’il pe, eyin ko gbodo josin fun olohun kan ayafi Allahu. Ki e si se daadaa si awon obi mejeeji, ibatan, awon omo orukan ati awon mekunnu. E ba awon eniyan soro rere. E kirun, ki e si yo Zakah. Leyin naa le peyin da afi die ninu yin. Eyin si n gbunri (kuro nibi adehun)

Choose other languages: