Surah Al-Bayyina Translated in Yoruba
لَمْ يَكُنِ الَّذِينَ كَفَرُوا مِنْ أَهْلِ الْكِتَابِ وَالْمُشْرِكِينَ مُنْفَكِّينَ حَتَّىٰ تَأْتِيَهُمُ الْبَيِّنَةُ
Awon t’o sai gbagbo ninu awon ahlul-kitab ati awon osebo, won ko nii kuro ninu aigbagbo won titi di igba ti eri t’o yanju yo fi maa de odo won
رَسُولٌ مِنَ اللَّهِ يَتْلُو صُحُفًا مُطَهَّرَةً
Ojise kan lati odo Allahu yo (si) maa ke awon takada mimo
وَمَا تَفَرَّقَ الَّذِينَ أُوتُوا الْكِتَابَ إِلَّا مِنْ بَعْدِ مَا جَاءَتْهُمُ الْبَيِّنَةُ
Awon ti A fun ni tira ko si di ijo otooto afi leyin ti eri t’o yanju de ba won
وَمَا أُمِرُوا إِلَّا لِيَعْبُدُوا اللَّهَ مُخْلِصِينَ لَهُ الدِّينَ حُنَفَاءَ وَيُقِيمُوا الصَّلَاةَ وَيُؤْتُوا الزَّكَاةَ ۚ وَذَٰلِكَ دِينُ الْقَيِّمَةِ
Awa ko si pa won ni ase kan bi ko se pe ki won josin fun Allahu (ki won je) oluse-afomo esin fun Un, oluduro deede. Ki won kirun, ki won si yo Zakah. Iyen si ni esin t’o fese rinle
إِنَّ الَّذِينَ كَفَرُوا مِنْ أَهْلِ الْكِتَابِ وَالْمُشْرِكِينَ فِي نَارِ جَهَنَّمَ خَالِدِينَ فِيهَا ۚ أُولَٰئِكَ هُمْ شَرُّ الْبَرِيَّةِ
Dajudaju awon t’o sai gbagbo (wonyi) ninu awon ahlul-kitab ati awon osebo, won yoo wa ninu Ina. Olusegbere ni won ninu re. Awon wonyen, awon ni eda t’o buru julo
إِنَّ الَّذِينَ آمَنُوا وَعَمِلُوا الصَّالِحَاتِ أُولَٰئِكَ هُمْ خَيْرُ الْبَرِيَّةِ
Dajudaju awon t’o gbagbo ni ododo (iyen, awon musulumi), ti won si se awon ise rere, awon wonyen, awon ni eda t’o dara julo
جَزَاؤُهُمْ عِنْدَ رَبِّهِمْ جَنَّاتُ عَدْنٍ تَجْرِي مِنْ تَحْتِهَا الْأَنْهَارُ خَالِدِينَ فِيهَا أَبَدًا ۖ رَضِيَ اللَّهُ عَنْهُمْ وَرَضُوا عَنْهُ ۚ ذَٰلِكَ لِمَنْ خَشِيَ رَبَّهُ
Esan won ni odo Oluwa won ni awon Ogba Idera gbere, ti awon odo n san ni isale re. Olusegbere ni won ninu re titi laelae. Allahu yonu si won. Awon naa yonu si (ohun ti Allahu fun won). Iyen wa fun enikeni ti o ba paya Oluwa re