Quran Apps in many lanuages:

Surah Al-Fath Translated in Yoruba

إِنَّا فَتَحْنَا لَكَ فَتْحًا مُبِينًا
Dajudaju Awa fun o ni isegun ponnbele
لِيَغْفِرَ لَكَ اللَّهُ مَا تَقَدَّمَ مِنْ ذَنْبِكَ وَمَا تَأَخَّرَ وَيُتِمَّ نِعْمَتَهُ عَلَيْكَ وَيَهْدِيَكَ صِرَاطًا مُسْتَقِيمًا
nitori ki Allahu le saforijin ohun ti o siwaju ninu asise re ati ohun ti o keyin (ninu re), ati nitori ki O le sasepe idera Re le o lori ati nitori ki O le fi ese re rinle soju ona taara (’Islam)
وَيَنْصُرَكَ اللَّهُ نَصْرًا عَزِيزًا
ati nitori ki Allahu le saranse fun o ni aranse t’o lagbara
هُوَ الَّذِي أَنْزَلَ السَّكِينَةَ فِي قُلُوبِ الْمُؤْمِنِينَ لِيَزْدَادُوا إِيمَانًا مَعَ إِيمَانِهِمْ ۗ وَلِلَّهِ جُنُودُ السَّمَاوَاتِ وَالْأَرْضِ ۚ وَكَانَ اللَّهُ عَلِيمًا حَكِيمًا
Oun ni Eni ti O so ifayabale sinu okan awon onigbagbo ododo nitori ki won le lekun ni igbagbo si igbagbo won. Ti Allahu si ni awon omo ogun sanmo ati ile. Allahu si n je Onimo, Ologbon
لِيُدْخِلَ الْمُؤْمِنِينَ وَالْمُؤْمِنَاتِ جَنَّاتٍ تَجْرِي مِنْ تَحْتِهَا الْأَنْهَارُ خَالِدِينَ فِيهَا وَيُكَفِّرَ عَنْهُمْ سَيِّئَاتِهِمْ ۚ وَكَانَ ذَٰلِكَ عِنْدَ اللَّهِ فَوْزًا عَظِيمًا
(O se bee fun won) nitori ki O le mu awon onigbagbo ododo lokunrin ati onigbagbo ododo lobinrin wo inu awon Ogba Idera, eyi ti awon odo n san ni isale re, olusegbere ni won ninu re, ati nitori ki O le pa awon asise won re. Iyen si je erenje nla ni odo Allahu
وَيُعَذِّبَ الْمُنَافِقِينَ وَالْمُنَافِقَاتِ وَالْمُشْرِكِينَ وَالْمُشْرِكَاتِ الظَّانِّينَ بِاللَّهِ ظَنَّ السَّوْءِ ۚ عَلَيْهِمْ دَائِرَةُ السَّوْءِ ۖ وَغَضِبَ اللَّهُ عَلَيْهِمْ وَلَعَنَهُمْ وَأَعَدَّ لَهُمْ جَهَنَّمَ ۖ وَسَاءَتْ مَصِيرًا
Ati nitori ki O le fiya je awon sobe-selu musulumi lokunrin ati awon sobe-selu musulumi lobinrin, pelu awon osebo lokunrin ati awon osebo lobinrin, awon elerokero nipa Allahu ni ti ero aburu. Apadasi aburu n be fun won. Allahu ti binu si won. O ti sebi le won. O si ti pese ina Jahnamo sile de won. O si buru ni ikangun
وَلِلَّهِ جُنُودُ السَّمَاوَاتِ وَالْأَرْضِ ۚ وَكَانَ اللَّهُ عَزِيزًا حَكِيمًا
Ti Allahu si ni awon omo ogun sanmo ati ile. Allahu si n je Alagbara, Ologbon
إِنَّا أَرْسَلْنَاكَ شَاهِدًا وَمُبَشِّرًا وَنَذِيرًا
Dajudaju Awa ran o nise (pe ki o je) olujerii, oniroo-idunnu ati olukilo
لِتُؤْمِنُوا بِاللَّهِ وَرَسُولِهِ وَتُعَزِّرُوهُ وَتُوَقِّرُوهُ وَتُسَبِّحُوهُ بُكْرَةً وَأَصِيلًا
nitori ki e le ni igbagbo ododo ninu Allahu ati Ojise Re, ati (nitori ki) e le se iranlowo fun (Ojise naa) ati nitori ki e le pataki re, ati nitori ki e le safomo fun (Allahu) ni owuro ati ni asale
إِنَّ الَّذِينَ يُبَايِعُونَكَ إِنَّمَا يُبَايِعُونَ اللَّهَ يَدُ اللَّهِ فَوْقَ أَيْدِيهِمْ ۚ فَمَنْ نَكَثَ فَإِنَّمَا يَنْكُثُ عَلَىٰ نَفْسِهِ ۖ وَمَنْ أَوْفَىٰ بِمَا عَاهَدَ عَلَيْهُ اللَّهَ فَسَيُؤْتِيهِ أَجْرًا عَظِيمًا
Dajudaju awon t’o n sadehun fun o (pe awon ko nii fese fee loju ogun), dajudaju Allahu ni won n sadehun fun. Owo Allahu wa loke owo won. Enikeni ti o ba tu adehun re, o tu u fun emi ara re. Enikeni ti o ba si mu adehun t’o se fun Allahu se, (Allahu) yoo fun un ni esan nla
Load More