Surah Al-Hadid Translated in Yoruba
سَبَّحَ لِلَّهِ مَا فِي السَّمَاوَاتِ وَالْأَرْضِ ۖ وَهُوَ الْعَزِيزُ الْحَكِيمُ
Ohunkohun t’o wa ninu awon sanmo ati ile n safomo fun Allahu. Oun si ni Alagbara, Ologbon
لَهُ مُلْكُ السَّمَاوَاتِ وَالْأَرْضِ ۖ يُحْيِي وَيُمِيتُ ۖ وَهُوَ عَلَىٰ كُلِّ شَيْءٍ قَدِيرٌ
TiRe ni ijoba awon sanmo ati ile. O n so eda di alaaye. O si n so eda di oku. Oun ni Alagbara lori gbogbo nnkan
هُوَ الْأَوَّلُ وَالْآخِرُ وَالظَّاهِرُ وَالْبَاطِنُ ۖ وَهُوَ بِكُلِّ شَيْءٍ عَلِيمٌ
Oun ni Akoko ati Ikeyin. O han (pelu ami bibe Re). O si pamo (fun gbogbo oju nile aye). Oun ni Onimo nipa gbogbo nnkan
هُوَ الَّذِي خَلَقَ السَّمَاوَاتِ وَالْأَرْضَ فِي سِتَّةِ أَيَّامٍ ثُمَّ اسْتَوَىٰ عَلَى الْعَرْشِ ۚ يَعْلَمُ مَا يَلِجُ فِي الْأَرْضِ وَمَا يَخْرُجُ مِنْهَا وَمَا يَنْزِلُ مِنَ السَّمَاءِ وَمَا يَعْرُجُ فِيهَا ۖ وَهُوَ مَعَكُمْ أَيْنَ مَا كُنْتُمْ ۚ وَاللَّهُ بِمَا تَعْمَلُونَ بَصِيرٌ
Oun ni Eni ti O seda awon sanmo ati ile fun ojo mefa. Leyin naa, O gunwa si ori Ite-ola. O mo nnkan t’o n wo inu ile ati nnkan t’o n jade lati inu re, ati nnkan t’o n sokale lati inu sanmo ati nnkan t’o n gunke sinu re. Ati pe O wa pelu yin ni ibikibi ti e ba wa (pelu imo Re). Allahu si ni Oluriran nipa ohun ti e n se nise
لَهُ مُلْكُ السَّمَاوَاتِ وَالْأَرْضِ ۚ وَإِلَى اللَّهِ تُرْجَعُ الْأُمُورُ
TiRe ni ijoba awon sanmo ati ile. Odo Allahu si ni won maa seri awon oro eda pada si
يُولِجُ اللَّيْلَ فِي النَّهَارِ وَيُولِجُ النَّهَارَ فِي اللَّيْلِ ۚ وَهُوَ عَلِيمٌ بِذَاتِ الصُّدُورِ
O n ti oru bo inu osan. O si n ti osan bo inu oru. Oun si ni Onimo nipa ohun t’o wa ninu igba-aya eda
آمِنُوا بِاللَّهِ وَرَسُولِهِ وَأَنْفِقُوا مِمَّا جَعَلَكُمْ مُسْتَخْلَفِينَ فِيهِ ۖ فَالَّذِينَ آمَنُوا مِنْكُمْ وَأَنْفَقُوا لَهُمْ أَجْرٌ كَبِيرٌ
E gbagbo ninu Allahu ati Ojise Re. Ki e si na ninu ohun ti O fi yin se arole lori re. Nitori naa, awon t’o gbagbo ni ododo ninu yin, ti won si nawo (si oju ona esin), esan t’o tobi wa fun won
وَمَا لَكُمْ لَا تُؤْمِنُونَ بِاللَّهِ ۙ وَالرَّسُولُ يَدْعُوكُمْ لِتُؤْمِنُوا بِرَبِّكُمْ وَقَدْ أَخَذَ مِيثَاقَكُمْ إِنْ كُنْتُمْ مُؤْمِنِينَ
Ki ni o mu yin ti eyin ko fi nii gba Allahu gbo ni ododo? Ojise si n pe yin nitori ki e le gba Oluwa yin gbo. Allahu si ti gba adehun lowo yin, ti eyin ba je onigbagbo ododo
هُوَ الَّذِي يُنَزِّلُ عَلَىٰ عَبْدِهِ آيَاتٍ بَيِّنَاتٍ لِيُخْرِجَكُمْ مِنَ الظُّلُمَاتِ إِلَى النُّورِ ۚ وَإِنَّ اللَّهَ بِكُمْ لَرَءُوفٌ رَحِيمٌ
Oun ni Eni t’O n so awon ayah t’o yanju kale fun erusin Re nitori ki o le mu yin kuro ninu awon okunkun wa sinu imole. Dajudaju Allahu ni Alaaanu, Asake-orun fun yin
وَمَا لَكُمْ أَلَّا تُنْفِقُوا فِي سَبِيلِ اللَّهِ وَلِلَّهِ مِيرَاثُ السَّمَاوَاتِ وَالْأَرْضِ ۚ لَا يَسْتَوِي مِنْكُمْ مَنْ أَنْفَقَ مِنْ قَبْلِ الْفَتْحِ وَقَاتَلَ ۚ أُولَٰئِكَ أَعْظَمُ دَرَجَةً مِنَ الَّذِينَ أَنْفَقُوا مِنْ بَعْدُ وَقَاتَلُوا ۚ وَكُلًّا وَعَدَ اللَّهُ الْحُسْنَىٰ ۚ وَاللَّهُ بِمَا تَعْمَلُونَ خَبِيرٌ
Ki ni o mu yin ti eyin ko fi nii nawo fun esin Allahu? Ti Allahu si ni ogun awon sanmo ati ile. Eni ti o nawo siwaju sisi ilu Mokkah, ti o tun jagun esin, ko dogba laaarin yin (si awon miiran). Awon wonyen ni esan won tobi julo si ti awon t’o nawo leyin igba naa, ti won tun jagun esin. Eni kookan si ni Allahu s’adehun esan rere fun. Allahu si ni Alamotan nipa ohun ti e n se nise
Load More