Surah Al-Hajj Translated in Yoruba
يَا أَيُّهَا النَّاسُ اتَّقُوا رَبَّكُمْ ۚ إِنَّ زَلْزَلَةَ السَّاعَةِ شَيْءٌ عَظِيمٌ
Eyin eniyan, e beru Oluwa yin. Dajudaju imi titi Akoko naa, nnkan nla ni
يَوْمَ تَرَوْنَهَا تَذْهَلُ كُلُّ مُرْضِعَةٍ عَمَّا أَرْضَعَتْ وَتَضَعُ كُلُّ ذَاتِ حَمْلٍ حَمْلَهَا وَتَرَى النَّاسَ سُكَارَىٰ وَمَا هُمْ بِسُكَارَىٰ وَلَٰكِنَّ عَذَابَ اللَّهِ شَدِيدٌ
(Akoko naa ni) ojo ti e maa ri i ti gbogbo obinrin t’o n fun omo lomu mu yoo gbagbe omo ti won n fun lomu ati pe gbogbo aboyun yo si maa bi oyun won. Iwo yo si ri awon eniyan ti oti yoo maa pa won. Oti ko si pa won, sugbon iya Allahu (t’o) le (l’o fa a)
وَمِنَ النَّاسِ مَنْ يُجَادِلُ فِي اللَّهِ بِغَيْرِ عِلْمٍ وَيَتَّبِعُ كُلَّ شَيْطَانٍ مَرِيدٍ
O si n be ninu awon eniyan eni t’o n jiyan nipa (esin) Allahu lai ni imo. O si n tele gbogbo esu olori kunkun
كُتِبَ عَلَيْهِ أَنَّهُ مَنْ تَوَلَّاهُ فَأَنَّهُ يُضِلُّهُ وَيَهْدِيهِ إِلَىٰ عَذَابِ السَّعِيرِ
Won ko o le (Esu) lori pe dajudaju enikeni ti o ba tele e, o maa si i lona. O si maa to o si ona iya Ina t’o n jo fofo
يَا أَيُّهَا النَّاسُ إِنْ كُنْتُمْ فِي رَيْبٍ مِنَ الْبَعْثِ فَإِنَّا خَلَقْنَاكُمْ مِنْ تُرَابٍ ثُمَّ مِنْ نُطْفَةٍ ثُمَّ مِنْ عَلَقَةٍ ثُمَّ مِنْ مُضْغَةٍ مُخَلَّقَةٍ وَغَيْرِ مُخَلَّقَةٍ لِنُبَيِّنَ لَكُمْ ۚ وَنُقِرُّ فِي الْأَرْحَامِ مَا نَشَاءُ إِلَىٰ أَجَلٍ مُسَمًّى ثُمَّ نُخْرِجُكُمْ طِفْلًا ثُمَّ لِتَبْلُغُوا أَشُدَّكُمْ ۖ وَمِنْكُمْ مَنْ يُتَوَفَّىٰ وَمِنْكُمْ مَنْ يُرَدُّ إِلَىٰ أَرْذَلِ الْعُمُرِ لِكَيْلَا يَعْلَمَ مِنْ بَعْدِ عِلْمٍ شَيْئًا ۚ وَتَرَى الْأَرْضَ هَامِدَةً فَإِذَا أَنْزَلْنَا عَلَيْهَا الْمَاءَ اهْتَزَّتْ وَرَبَتْ وَأَنْبَتَتْ مِنْ كُلِّ زَوْجٍ بَهِيجٍ
Eyin eniyan, ti e ba wa ninu iyemeji nipa ajinde, dajudaju Awa seda yin lati inu erupe, leyin naa lati inu ato, leyin naa lati inu eje didi, leyin naa lati inu baasi eran ti o pe ni eda ati eyi ti ko pe ni eda nitori ki A le salaye (agbara Wa) fun yin. A si n mu ohun ti A ba fe duro sinu apo ibimo titi di gbedeke akoko kan. Leyin naa, A oo mu yin jade ni oponlo. Leyin naa, (e oo maa semi lo) nitori ki e le sanngun dopin agbara yin. Eni ti o maa ku (ni kekere) wa ninu yin. O si wa ninu yin eni ti A oo da (isemi) re si di asiko ogbo kujokujo nitori ki o ma le mo nnkan kan mo leyin ti o ti mo on. Ati pe o maa ri ile ni gbigbe. Nigba ti A ba si so ojo kale le e lori, o maa yira pada. O maa gberu. O si maa mu gbogbo orisirisi irugbin t’o dara jade
ذَٰلِكَ بِأَنَّ اللَّهَ هُوَ الْحَقُّ وَأَنَّهُ يُحْيِي الْمَوْتَىٰ وَأَنَّهُ عَلَىٰ كُلِّ شَيْءٍ قَدِيرٌ
Iyen nitori pe dajudaju Allahu, Oun ni Ododo. Dajudaju Oun l’O n so awon oku di alaaye. Dajudaju Oun si ni Alagbara lori gbogbo nnkan
وَأَنَّ السَّاعَةَ آتِيَةٌ لَا رَيْبَ فِيهَا وَأَنَّ اللَّهَ يَبْعَثُ مَنْ فِي الْقُبُورِ
Ati pe dajudaju Akoko naa n bo. Ko si iyemeji ninu re. Dajudaju Allahu yoo gbe awon t’o n be ninu saree dide
وَمِنَ النَّاسِ مَنْ يُجَادِلُ فِي اللَّهِ بِغَيْرِ عِلْمٍ وَلَا هُدًى وَلَا كِتَابٍ مُنِيرٍ
O n be ninu awon eniyan eni t’o n jiyan nipa (esin) Allahu lai ni imo (al-Ƙur’an) ati imona (sunnah Anabi) ati tira (onimo-esin) t’o n tan imole (soro esin)
ثَانِيَ عِطْفِهِ لِيُضِلَّ عَنْ سَبِيلِ اللَّهِ ۖ لَهُ فِي الدُّنْيَا خِزْيٌ ۖ وَنُذِيقُهُ يَوْمَ الْقِيَامَةِ عَذَابَ الْحَرِيقِ
O n yi orun re ka ni ti igberaga nitori ki o le ko isina ba awon eniyan loju ona (esin) Allahu. Abuku n be fun un nile aye. Ni Ojo Ajinde, A si maa fun un ni iya Ina jonijoni to wo
ذَٰلِكَ بِمَا قَدَّمَتْ يَدَاكَ وَأَنَّ اللَّهَ لَيْسَ بِظَلَّامٍ لِلْعَبِيدِ
Iyen nitori ohun ti owo re ti siwaju. Dajudaju Allahu ko nii sabosi si awon erusin Re
Load More