Surah Al-Hijr Translated in Yoruba
الر ۚ تِلْكَ آيَاتُ الْكِتَابِ وَقُرْآنٍ مُبِينٍ
’Alif lam ro. Iwonyi ni awon ayah Tira naa ati (awon ayah) al-Ƙur’an t’o n yanju oro eda
رُبَمَا يَوَدُّ الَّذِينَ كَفَرُوا لَوْ كَانُوا مُسْلِمِينَ
O see se ki awon t’o sai gbagbo nifee si pe awon iba si ti je musulumi (nile aye)
ذَرْهُمْ يَأْكُلُوا وَيَتَمَتَّعُوا وَيُلْهِهِمُ الْأَمَلُ ۖ فَسَوْفَ يَعْلَمُونَ
Fi won sile, ki won je, ki won gbadun, ki ireti (emi gigun) ko airoju raaye ba won (lati sesin); laipe won maa mo
وَمَا أَهْلَكْنَا مِنْ قَرْيَةٍ إِلَّا وَلَهَا كِتَابٌ مَعْلُومٌ
A ko pa ilu kan run ri afi ki o ni akosile ti A ti mo
مَا تَسْبِقُ مِنْ أُمَّةٍ أَجَلَهَا وَمَا يَسْتَأْخِرُونَ
Ko si ijo kan (ti o parun) siwaju akoko re (ninu Laohul-Mahfuuth); won ko si nii sun un siwaju fun won
وَقَالُوا يَا أَيُّهَا الَّذِي نُزِّلَ عَلَيْهِ الذِّكْرُ إِنَّكَ لَمَجْنُونٌ
Won wi pe: “Iwo ti Won so al-Ƙur’an kale fun, dajudaju were ni e
لَوْ مَا تَأْتِينَا بِالْمَلَائِكَةِ إِنْ كُنْتَ مِنَ الصَّادِقِينَ
Ki ni ko je ki iwo mu awon molaika wa ba wa, ti iwo ba wa ninu awon olododo?”
مَا نُنَزِّلُ الْمَلَائِكَةَ إِلَّا بِالْحَقِّ وَمَا كَانُوا إِذًا مُنْظَرِينَ
A o nii so molaika kale bi ko se pelu ododo. Won ko si nii lo won lara mo nigba naa (ti awon molaika ba sokale)
إِنَّا نَحْنُ نَزَّلْنَا الذِّكْرَ وَإِنَّا لَهُ لَحَافِظُونَ
Dajudaju Awa l’A so Tira Iranti kale (iyen al-Ƙur’an). Dajudaju Awa si ni Oluso re
وَلَقَدْ أَرْسَلْنَا مِنْ قَبْلِكَ فِي شِيَعِ الْأَوَّلِينَ
Dajudaju siwaju re A ti ran (awon Ojise) nise si awon ijo, awon eni akoko
Load More