Surah Al-Hujraat Translated in Yoruba
يَا أَيُّهَا الَّذِينَ آمَنُوا لَا تُقَدِّمُوا بَيْنَ يَدَيِ اللَّهِ وَرَسُولِهِ ۖ وَاتَّقُوا اللَّهَ ۚ إِنَّ اللَّهَ سَمِيعٌ عَلِيمٌ
Eyin ti e gbagbo ni ododo, eyin ko gbodo gbawaju mo Allahu ati Ojise Re lowo. Ki e si beru Allahu. Dajudaju Allahu ni Olugbo, Onimo
يَا أَيُّهَا الَّذِينَ آمَنُوا لَا تَرْفَعُوا أَصْوَاتَكُمْ فَوْقَ صَوْتِ النَّبِيِّ وَلَا تَجْهَرُوا لَهُ بِالْقَوْلِ كَجَهْرِ بَعْضِكُمْ لِبَعْضٍ أَنْ تَحْبَطَ أَعْمَالُكُمْ وَأَنْتُمْ لَا تَشْعُرُونَ
Eyin ti e gbagbo ni ododo, e ma se gbe ohun yin ga bori ohun Anabi (sollalahu alayhi wa sallam). Ki e si ma se fi ohun ariwo ba a soro gege bi apa kan yin se n fi ohun ariwo ba apa kan soro nitori ki awon ise yin ma baa baje, eyin ko si nii fura
إِنَّ الَّذِينَ يَغُضُّونَ أَصْوَاتَهُمْ عِنْدَ رَسُولِ اللَّهِ أُولَٰئِكَ الَّذِينَ امْتَحَنَ اللَّهُ قُلُوبَهُمْ لِلتَّقْوَىٰ ۚ لَهُمْ مَغْفِرَةٌ وَأَجْرٌ عَظِيمٌ
Dajudaju awon t’o n re ohun won nile lodo Ojise Allahu, awon wonyen ni awon ti Allahu ti gbidanwo okan won fun iberu (Re). Aforijin ati esan nla wa fun won
إِنَّ الَّذِينَ يُنَادُونَكَ مِنْ وَرَاءِ الْحُجُرَاتِ أَكْثَرُهُمْ لَا يَعْقِلُونَ
Dajudaju awon t’o n pe o lati eyin awon yara, opolopo won ni ko se laakaye
وَلَوْ أَنَّهُمْ صَبَرُوا حَتَّىٰ تَخْرُجَ إِلَيْهِمْ لَكَانَ خَيْرًا لَهُمْ ۚ وَاللَّهُ غَفُورٌ رَحِيمٌ
Ti o ba je pe dajudaju won se suuru titi o maa fi jade si won ni, iba dara julo fun won. Allahu si ni Alaforijin, Asake-orun
يَا أَيُّهَا الَّذِينَ آمَنُوا إِنْ جَاءَكُمْ فَاسِقٌ بِنَبَإٍ فَتَبَيَّنُوا أَنْ تُصِيبُوا قَوْمًا بِجَهَالَةٍ فَتُصْبِحُوا عَلَىٰ مَا فَعَلْتُمْ نَادِمِينَ
Eyin ti e gbagbo ni ododo, ti obileje kan ba mu iro kan wa ba yin, e se pelepele lati mo ododo (nipa oro naa) nitori ki e ma baa se awon eniyan kan ni suta pelu aimo. Leyin naa, ki e ma baa di alabaamo lori ohun ti e se
وَاعْلَمُوا أَنَّ فِيكُمْ رَسُولَ اللَّهِ ۚ لَوْ يُطِيعُكُمْ فِي كَثِيرٍ مِنَ الْأَمْرِ لَعَنِتُّمْ وَلَٰكِنَّ اللَّهَ حَبَّبَ إِلَيْكُمُ الْإِيمَانَ وَزَيَّنَهُ فِي قُلُوبِكُمْ وَكَرَّهَ إِلَيْكُمُ الْكُفْرَ وَالْفُسُوقَ وَالْعِصْيَانَ ۚ أُولَٰئِكَ هُمُ الرَّاشِدُونَ
Ki e si mo pe dajudaju Ojise Allahu wa laarin yin. Ti o ba je pe o n tele yin nibi opolopo ninu oro (t’o n sele) ni, dajudaju eyin iba ti ko o sinu idaamu. Sugbon Allahu je ki e nifee si igbagbo ododo. O se e ni oso sinu okan yin. O si je ki e korira aigbagbo, iwa buruku ati iyapa ase. Awon wonyen ni awon olumona
فَضْلًا مِنَ اللَّهِ وَنِعْمَةً ۚ وَاللَّهُ عَلِيمٌ حَكِيمٌ
(Eyi je) oore ajulo ati idera lati odo Allahu. Allahu si ni Onimo, Ologbon
وَإِنْ طَائِفَتَانِ مِنَ الْمُؤْمِنِينَ اقْتَتَلُوا فَأَصْلِحُوا بَيْنَهُمَا ۖ فَإِنْ بَغَتْ إِحْدَاهُمَا عَلَى الْأُخْرَىٰ فَقَاتِلُوا الَّتِي تَبْغِي حَتَّىٰ تَفِيءَ إِلَىٰ أَمْرِ اللَّهِ ۚ فَإِنْ فَاءَتْ فَأَصْلِحُوا بَيْنَهُمَا بِالْعَدْلِ وَأَقْسِطُوا ۖ إِنَّ اللَّهَ يُحِبُّ الْمُقْسِطِينَ
Ti igun meji ninu awon onigbagbo ododo ba n ba ara won ja, e se atunse laaarin awon mejeeji. Ti okan ninu awon mejeeji ba si koja enu-ala lori ikeji, e ba eyi ti o koja enu-ala ja titi o fi maa seri pada sibi ase Allahu. Ti o ba si seri pada, e se atunse laaarin awon mejeeji pelu deede. Ki e si se eto. Dajudaju Allahu feran awon oluse-eto
إِنَّمَا الْمُؤْمِنُونَ إِخْوَةٌ فَأَصْلِحُوا بَيْنَ أَخَوَيْكُمْ ۚ وَاتَّقُوا اللَّهَ لَعَلَّكُمْ تُرْحَمُونَ
Omo iya (esin) ni awon onigbagbo ododo. Nitori naa, e satunse laaarin awon omo iya yin mejeeji. Ki e si beru Allahu nitori ki A le ke yin
Load More