Quran Apps in many lanuages:

Surah Al-Insan Translated in Yoruba

هَلْ أَتَىٰ عَلَى الْإِنْسَانِ حِينٌ مِنَ الدَّهْرِ لَمْ يَكُنْ شَيْئًا مَذْكُورًا
Sebi akoko kan ninu igba ti re koja lori eniyan ti (eniyan) ko je kini kan ti won n daruko
إِنَّا خَلَقْنَا الْإِنْسَانَ مِنْ نُطْفَةٍ أَمْشَاجٍ نَبْتَلِيهِ فَجَعَلْنَاهُ سَمِيعًا بَصِيرًا
Dajudaju Awa seda eniyan lati ara ato t’o ropo mora won (lati ara okunrin ati obinrin), ki A le dan an wo. A si se e ni olugbo, oluriran
إِنَّا هَدَيْنَاهُ السَّبِيلَ إِمَّا شَاكِرًا وَإِمَّا كَفُورًا
Dajudaju A fi ona mo on; O le je oludupe, o si le je alaimoore
إِنَّا أَعْتَدْنَا لِلْكَافِرِينَ سَلَاسِلَ وَأَغْلَالًا وَسَعِيرًا
Dajudaju Awa pese awon ewon, ajaga ati Ina sile de awon alaigbagbo
إِنَّ الْأَبْرَارَ يَشْرَبُونَ مِنْ كَأْسٍ كَانَ مِزَاجُهَا كَافُورًا
Dajudaju awon eni rere, won yoo maa mu omi kan ninu ife. Ohun ti A popo mo (omi naa) ni kafura
عَيْنًا يَشْرَبُ بِهَا عِبَادُ اللَّهِ يُفَجِّرُونَهَا تَفْجِيرًا
Omi iseleru kan ni, ti awon erusin Allahu yoo maa mu, ti won yo si maa mu un san jade daadaa (si ibi ti won ba fe)
يُوفُونَ بِالنَّذْرِ وَيَخَافُونَ يَوْمًا كَانَ شَرُّهُ مُسْتَطِيرًا
Won n mu eje won se. Won si n paya ojo kan, ti aburu re je ohun ti o maa fonka gan-an
وَيُطْعِمُونَ الطَّعَامَ عَلَىٰ حُبِّهِ مِسْكِينًا وَيَتِيمًا وَأَسِيرًا
Tohun ti bi won se ni ife si (oro to), won n fun mekunnu, omo orukan ati eru ni ounje je
إِنَّمَا نُطْعِمُكُمْ لِوَجْهِ اللَّهِ لَا نُرِيدُ مِنْكُمْ جَزَاءً وَلَا شُكُورًا
(Won si n so pe:) "Nitori Oju rere Allahu (nikan) l’a fi n fun yin ni ounje; awa ko si gbero esan tabi idupe kan lati odo yin
إِنَّا نَخَافُ مِنْ رَبِّنَا يَوْمًا عَبُوسًا قَمْطَرِيرًا
Dajudaju awa n paya ni odo Oluwa wa ojo kan ti (eda yoo) faju ro koko
Load More