Quran Apps in many lanuages:

Surah Al-Isra Translated in Yoruba

سُبْحَانَ الَّذِي أَسْرَىٰ بِعَبْدِهِ لَيْلًا مِنَ الْمَسْجِدِ الْحَرَامِ إِلَى الْمَسْجِدِ الْأَقْصَى الَّذِي بَارَكْنَا حَوْلَهُ لِنُرِيَهُ مِنْ آيَاتِنَا ۚ إِنَّهُ هُوَ السَّمِيعُ الْبَصِيرُ
Mimo ni fun Eni ti O mu erusin Re se irin-ajo ni ale lati Mosalasi Haram si Mosalasi Aƙso ti A fi ibukun yi ka, nitori ki A le fi ninu awon ami Wa han an. Dajudaju Allahu, Oun ni Olugbo, Oluriran
وَآتَيْنَا مُوسَى الْكِتَابَ وَجَعَلْنَاهُ هُدًى لِبَنِي إِسْرَائِيلَ أَلَّا تَتَّخِذُوا مِنْ دُونِي وَكِيلًا
A fun (Anabi) Musa ni Tira. A si se e ni imona fun awon omo ’Isro’il. (A si so) pe: “E ma se mu alaabo kan leyin Mi.”
ذُرِّيَّةَ مَنْ حَمَلْنَا مَعَ نُوحٍ ۚ إِنَّهُ كَانَ عَبْدًا شَكُورًا
(E je) aromodomo awon ti A gbe gun oko oju-omi pelu (Anabi) Nuh. Dajudaju (Nuh) je erusin, oludupe
وَقَضَيْنَا إِلَىٰ بَنِي إِسْرَائِيلَ فِي الْكِتَابِ لَتُفْسِدُنَّ فِي الْأَرْضِ مَرَّتَيْنِ وَلَتَعْلُنَّ عُلُوًّا كَبِيرًا
A si fi mo awon omo ’Isro’il ninu Tira pe: “Dajudaju e maa sebaje lori ile nigba meji. Dajudaju e tun maa segberaga t’o tobi.”
فَإِذَا جَاءَ وَعْدُ أُولَاهُمَا بَعَثْنَا عَلَيْكُمْ عِبَادًا لَنَا أُولِي بَأْسٍ شَدِيدٍ فَجَاسُوا خِلَالَ الدِّيَارِ ۚ وَكَانَ وَعْدًا مَفْعُولًا
Nitori naa, nigba ti adehun fun akoko ninu mejeeji ba sele, A maa gbe awon erusin Wa kan, ti won lagbara gan-an, dide si yin. Won yoo da rogbodiyan sile laaarin ilu (yin). O je adehun kan ti A maa mu se
ثُمَّ رَدَدْنَا لَكُمُ الْكَرَّةَ عَلَيْهِمْ وَأَمْدَدْنَاكُمْ بِأَمْوَالٍ وَبَنِينَ وَجَعَلْنَاكُمْ أَكْثَرَ نَفِيرًا
Leyin naa, A da isegun lori won pada fun yin. A si fi awon dukia ati awon omo se idera fun yin. A si se yin ni ijo t’o po julo
إِنْ أَحْسَنْتُمْ أَحْسَنْتُمْ لِأَنْفُسِكُمْ ۖ وَإِنْ أَسَأْتُمْ فَلَهَا ۚ فَإِذَا جَاءَ وَعْدُ الْآخِرَةِ لِيَسُوءُوا وُجُوهَكُمْ وَلِيَدْخُلُوا الْمَسْجِدَ كَمَا دَخَلُوهُ أَوَّلَ مَرَّةٍ وَلِيُتَبِّرُوا مَا عَلَوْا تَتْبِيرًا
Ti e ba se rere, e se rere fun emi ara yin. Ti e ba si se aburu, fun emi ara yin ni. Nigba ti adehun ikeyin ba de, (A oo gbe omo ogun miiran dide) nitori ki won le ko ibanuje ba yin ati nitori ki won le wo inu Mosalasi gege bi won se wo o nigba akoko ati nitori ki won le pa ohun ti (awon omo ’Isro’il) joba lori re run patapata
عَسَىٰ رَبُّكُمْ أَنْ يَرْحَمَكُمْ ۚ وَإِنْ عُدْتُمْ عُدْنَا ۘ وَجَعَلْنَا جَهَنَّمَ لِلْكَافِرِينَ حَصِيرًا
O le je pe Oluwa yin maa saanu yin. Ti e ba si pada (sibi ese), A maa pada (sibi esan). A si se ina Jahanamo ni ewon fun awon alaigbagbo
إِنَّ هَٰذَا الْقُرْآنَ يَهْدِي لِلَّتِي هِيَ أَقْوَمُ وَيُبَشِّرُ الْمُؤْمِنِينَ الَّذِينَ يَعْمَلُونَ الصَّالِحَاتِ أَنَّ لَهُمْ أَجْرًا كَبِيرًا
Dajudaju al-Ƙur’an yii, o n fini mona si ona taara, o si n fun awon onigbagbo ododo t’o n se awon ise rere ni iro idunnu pe dajudaju esan t’o tobi wa fun won
وَأَنَّ الَّذِينَ لَا يُؤْمِنُونَ بِالْآخِرَةِ أَعْتَدْنَا لَهُمْ عَذَابًا أَلِيمًا
Dajudaju awon ti ko gba Ojo Ikeyin gbo, A ti pese iya eleta-elero sile de won
Load More