Quran Apps in many lanuages:

Surah Al-Jinn Translated in Yoruba

قُلْ أُوحِيَ إِلَيَّ أَنَّهُ اسْتَمَعَ نَفَرٌ مِنَ الْجِنِّ فَقَالُوا إِنَّا سَمِعْنَا قُرْآنًا عَجَبًا
So pe: "Won fi imisi ranse si mi pe dajudaju ijo kan ninu awon alujannu teti (si al-Ƙur’an)." Won si so pe: "Dajudaju awa gbo al-Ƙur’an iyanu
يَهْدِي إِلَى الرُّشْدِ فَآمَنَّا بِهِ ۖ وَلَنْ نُشْرِكَ بِرَبِّنَا أَحَدًا
O n setosona sibi imona. Nitori naa, a gba a gbo. Awa ko si nii fi eni kan kan se akegbe fun Oluwa wa
وَأَنَّهُ تَعَالَىٰ جَدُّ رَبِّنَا مَا اتَّخَذَ صَاحِبَةً وَلَا وَلَدًا
Ati pe dajudaju titobi Oluwa wa ga. Ko fi eni kan kan se aya ati omo
وَأَنَّهُ كَانَ يَقُولُ سَفِيهُنَا عَلَى اللَّهِ شَطَطًا
Dajudaju omugo ninu wa maa n so isokuso nipa Allahu
وَأَنَّا ظَنَنَّا أَنْ لَنْ تَقُولَ الْإِنْسُ وَالْجِنُّ عَلَى اللَّهِ كَذِبًا
Dajudaju awa si n ro pe eniyan ati alujannu ko nii pa iro mo Allahu ni
وَأَنَّهُ كَانَ رِجَالٌ مِنَ الْإِنْسِ يَعُوذُونَ بِرِجَالٍ مِنَ الْجِنِّ فَزَادُوهُمْ رَهَقًا
Ati pe dajudaju awon okunrin kan ninu eniyan maa n fi awon okunrin kan ninu awon alujannu wa aabo. Awon alujannu si se alekun aburu fun won
وَأَنَّهُمْ ظَنُّوا كَمَا ظَنَنْتُمْ أَنْ لَنْ يَبْعَثَ اللَّهُ أَحَدًا
Dajudaju awon alujannu lero gege bi eyin eniyan naa se lero pe Allahu ko nii gbe eni kan kan dide (leyin iku)
وَأَنَّا لَمَسْنَا السَّمَاءَ فَوَجَدْنَاهَا مُلِئَتْ حَرَسًا شَدِيدًا وَشُهُبًا
Dajudaju awa wa (oro ayogbo) wa si sanmo, a si ba a ti o ti kun fun awon eso t’o lagbara ati awon ogunna
وَأَنَّا كُنَّا نَقْعُدُ مِنْهَا مَقَاعِدَ لِلسَّمْعِ ۖ فَمَنْ يَسْتَمِعِ الْآنَ يَجِدْ لَهُ شِهَابًا رَصَدًا
Dajudaju awa maa n jokoo sibe ni awon ibudo kan fun gbigbo oro. Sugbon eni t’o ba joro gbo lasiko yii, o maa ri ogunna t’o ti lugo de e
وَأَنَّا لَا نَدْرِي أَشَرٌّ أُرِيدَ بِمَنْ فِي الْأَرْضِ أَمْ أَرَادَ بِهِمْ رَبُّهُمْ رَشَدًا
Dajudaju awa ko si mo boya aburu ni won gba lero pelu awon t’o wa lori ile tabi Oluwa won gbero imona fun won
Load More