Surah Al-Kahf Translated in Yoruba
الْحَمْدُ لِلَّهِ الَّذِي أَنْزَلَ عَلَىٰ عَبْدِهِ الْكِتَابَ وَلَمْ يَجْعَلْ لَهُ عِوَجًا ۜ
Gbogbo ope n je ti Allahu, Eni ti O so Tira kale fun erusin Re. Ko si doju oro kan ru ninu re
قَيِّمًا لِيُنْذِرَ بَأْسًا شَدِيدًا مِنْ لَدُنْهُ وَيُبَشِّرَ الْمُؤْمِنِينَ الَّذِينَ يَعْمَلُونَ الصَّالِحَاتِ أَنَّ لَهُمْ أَجْرًا حَسَنًا
(al-Ƙur’an) fese rinle nitori ki (Anabi) le fi se ikilo iya lile lati odo (Allahu) ati nitori ki (Anabi) le fun awon onigbagbo ododo, awon t’o n se ise rere ni iro idunnu pe dajudaju esan rere n be fun won (ninu Ogba Idera)
وَيُنْذِرَ الَّذِينَ قَالُوا اتَّخَذَ اللَّهُ وَلَدًا
Ati nitori ki (Anabi) le se ikilo fun awon t’o wi pe: “Allahu mu eni kan ni omo.”
مَا لَهُمْ بِهِ مِنْ عِلْمٍ وَلَا لِآبَائِهِمْ ۚ كَبُرَتْ كَلِمَةً تَخْرُجُ مِنْ أَفْوَاهِهِمْ ۚ إِنْ يَقُولُونَ إِلَّا كَذِبًا
Ko si imo fun awon ati baba won nipa re. Oro t’o n jade lenu won tobi. Dajudaju won ko wi kini kan bi ko se iro
فَلَعَلَّكَ بَاخِعٌ نَفْسَكَ عَلَىٰ آثَارِهِمْ إِنْ لَمْ يُؤْمِنُوا بِهَٰذَا الْحَدِيثِ أَسَفًا
Nitori naa, nitori ki ni o se maa fi ibanuje para re lori igbese won pe won ko gba oro (al-Ƙur’an) yii gbo
إِنَّا جَعَلْنَا مَا عَلَى الْأَرْضِ زِينَةً لَهَا لِنَبْلُوَهُمْ أَيُّهُمْ أَحْسَنُ عَمَلًا
Dajudaju Awa se ohun ti n be lori ile ni oso fun ara-aye nitori ki A le dan won wo (pe) ewo ninu won l’o maa dara julo nibi ise sise (fun esin)
وَإِنَّا لَجَاعِلُونَ مَا عَلَيْهَا صَعِيدًا جُرُزًا
Ati pe dajudaju Awa maa so nnkan ti n be lori (ile) di erupe gbigbe ti ko nii hu irugbin
أَمْ حَسِبْتَ أَنَّ أَصْحَابَ الْكَهْفِ وَالرَّقِيمِ كَانُوا مِنْ آيَاتِنَا عَجَبًا
Tabi o lero pe dajudaju awon ara inu iho apata ati walaha oruko won je eemo kan ninu awon ami Wa
إِذْ أَوَى الْفِتْيَةُ إِلَى الْكَهْفِ فَقَالُوا رَبَّنَا آتِنَا مِنْ لَدُنْكَ رَحْمَةً وَهَيِّئْ لَنَا مِنْ أَمْرِنَا رَشَدًا
Nigba ti awon odokunrin naa kora won sinu iho apata, won so pe: “Oluwa wa, fun wa ni ike lati odo Re, ki O se imona ni irorun fun wa ninu oro wa.”
Load More