Quran Apps in many lanuages:

Surah Al-Mulk Translated in Yoruba

تَبَارَكَ الَّذِي بِيَدِهِ الْمُلْكُ وَهُوَ عَلَىٰ كُلِّ شَيْءٍ قَدِيرٌ
Ibukun ni fun Eni ti ijoba wa ni Owo Re. Oun si ni Alagbara lori gbogbo nnkan
الَّذِي خَلَقَ الْمَوْتَ وَالْحَيَاةَ لِيَبْلُوَكُمْ أَيُّكُمْ أَحْسَنُ عَمَلًا ۚ وَهُوَ الْعَزِيزُ الْغَفُورُ
Eni ti O da iku ati isemi nitori ki o le dan yin wo; ewo ninu yin l’o maa se ise rere julo. Oun si ni Alagbara, Alaforijin
الَّذِي خَلَقَ سَبْعَ سَمَاوَاتٍ طِبَاقًا ۖ مَا تَرَىٰ فِي خَلْقِ الرَّحْمَٰنِ مِنْ تَفَاوُتٍ ۖ فَارْجِعِ الْبَصَرَ هَلْ تَرَىٰ مِنْ فُطُورٍ
Eni ti O da awon sanmo meje ni ipele ipele. O o le ri aigunrege kan lara eda Ajoke-aye. Nitori naa, wo o pada, nje o ri oju sisan kan (lara sanmo)
ثُمَّ ارْجِعِ الْبَصَرَ كَرَّتَيْنِ يَنْقَلِبْ إِلَيْكَ الْبَصَرُ خَاسِئًا وَهُوَ حَسِيرٌ
Leyin naa, wo o pada ni ee meji, ki oju re pada si odo re pelu iyepere. O si maa kaaare
وَلَقَدْ زَيَّنَّا السَّمَاءَ الدُّنْيَا بِمَصَابِيحَ وَجَعَلْنَاهَا رُجُومًا لِلشَّيَاطِينِ ۖ وَأَعْتَدْنَا لَهُمْ عَذَابَ السَّعِيرِ
Dajudaju A ti fi (awon irawo t’o n tanmole bi) atupa se sanmo ile aye ni oso. A tun se won ni eta-irawo ti won n ju mo awon esu. A si pese iya Ina t’o n jo fofo sile de won
وَلِلَّذِينَ كَفَرُوا بِرَبِّهِمْ عَذَابُ جَهَنَّمَ ۖ وَبِئْسَ الْمَصِيرُ
Iya ina Jahanamo si wa fun awon t’o sai gbagbo. Ikangun naa si buru
إِذَا أُلْقُوا فِيهَا سَمِعُوا لَهَا شَهِيقًا وَهِيَ تَفُورُ
Nigba ti won ba ju won sinu re, won yoo maa gbo kikun re, ti o si maa ru soke
تَكَادُ تَمَيَّزُ مِنَ الْغَيْظِ ۖ كُلَّمَا أُلْقِيَ فِيهَا فَوْجٌ سَأَلَهُمْ خَزَنَتُهَا أَلَمْ يَأْتِكُمْ نَذِيرٌ
Ina maa fee pinra re lati ara ibinu. Igbakigba ti won ba ju ijo kan sinu re, awon eso Ina yoo maa bi won leere pe: "Nje olukilo kan ko wa ba yin bi
قَالُوا بَلَىٰ قَدْ جَاءَنَا نَذِيرٌ فَكَذَّبْنَا وَقُلْنَا مَا نَزَّلَ اللَّهُ مِنْ شَيْءٍ إِنْ أَنْتُمْ إِلَّا فِي ضَلَالٍ كَبِيرٍ
Won yoo wi pe: "Rara, dajudaju olukilo kan ti wa ba wa, sugbon a pe e ni opuro. A si wi pe Allahu ko so nnkan kan kale. Ki ni eyin bi ko se pe e wa ninu isina t’o tobi
وَقَالُوا لَوْ كُنَّا نَسْمَعُ أَوْ نَعْقِلُ مَا كُنَّا فِي أَصْحَابِ السَّعِيرِ
Won tun wi pe: "Ti o ba je pe a gboran ni tabi pe a se laakaye ni, awa ko nii wa ninu ero inu Ina jijo
Load More