Surah Al-Munafiqoon Translated in Yoruba
إِذَا جَاءَكَ الْمُنَافِقُونَ قَالُوا نَشْهَدُ إِنَّكَ لَرَسُولُ اللَّهِ ۗ وَاللَّهُ يَعْلَمُ إِنَّكَ لَرَسُولُهُ وَاللَّهُ يَشْهَدُ إِنَّ الْمُنَافِقِينَ لَكَاذِبُونَ
Nigba ti awon sobe-selu musulumi ba wa si odo re, won a wi pe: “A n jerii pe dajudaju iwo, Ojise Allahu ni o.” Allahu si mo pe dajudaju iwo, Ojise Re ni o. Allahu si n jerii pe dajudaju awon sobe-selu musulumi, opuro ni won
اتَّخَذُوا أَيْمَانَهُمْ جُنَّةً فَصَدُّوا عَنْ سَبِيلِ اللَّهِ ۚ إِنَّهُمْ سَاءَ مَا كَانُوا يَعْمَلُونَ
Won fi awon ibura won se aabo (fun emi ara won), won si seri awon eniyan kuro loju ona (esin) Allahu; dajudaju ohun ti won n se nise buru
ذَٰلِكَ بِأَنَّهُمْ آمَنُوا ثُمَّ كَفَرُوا فَطُبِعَ عَلَىٰ قُلُوبِهِمْ فَهُمْ لَا يَفْقَهُونَ
(Won se) iyen nitori pe won gbagbo, leyin naa won sai gbagbo. Nitori naa, A ti fi edidi di okan won; won ko si nii gbo agboye
وَإِذَا رَأَيْتَهُمْ تُعْجِبُكَ أَجْسَامُهُمْ ۖ وَإِنْ يَقُولُوا تَسْمَعْ لِقَوْلِهِمْ ۖ كَأَنَّهُمْ خُشُبٌ مُسَنَّدَةٌ ۖ يَحْسَبُونَ كُلَّ صَيْحَةٍ عَلَيْهِمْ ۚ هُمُ الْعَدُوُّ فَاحْذَرْهُمْ ۚ قَاتَلَهُمُ اللَّهُ ۖ أَنَّىٰ يُؤْفَكُونَ
Nigba ti o ba ri won, irisi won yoo jo o loju. Ti won ba n soro, iwo yoo teti gbo oro won. Won si da bi igi ti won gbe ti ogiri. Won si n lero pe gbogbo igbe (ibosi) n be lori won (nipa isobe-selu won). Ota ni won. Nitori naa, sora fun won. Allahu ti sebi le won. Bawo ni won se n seri won kuro nibi ododo
وَإِذَا قِيلَ لَهُمْ تَعَالَوْا يَسْتَغْفِرْ لَكُمْ رَسُولُ اللَّهِ لَوَّوْا رُءُوسَهُمْ وَرَأَيْتَهُمْ يَصُدُّونَ وَهُمْ مُسْتَكْبِرُونَ
Ati pe nigba ti won ba so fun won pe: “E wa ki Ojise ba yin toro aforijin.” Won a gbunri. O si maa ri won ti won yoo maa gbunri lo, ti won yoo maa segberaga
سَوَاءٌ عَلَيْهِمْ أَسْتَغْفَرْتَ لَهُمْ أَمْ لَمْ تَسْتَغْفِرْ لَهُمْ لَنْ يَغْفِرَ اللَّهُ لَهُمْ ۚ إِنَّ اللَّهَ لَا يَهْدِي الْقَوْمَ الْفَاسِقِينَ
Bakan naa ni fun won; yala o ba won toro aforijin tabi o o ba won toro aforijin. Allahu ko nii forijin won. Dajudaju Allahu ko nii fi ona mo ijo obileje
هُمُ الَّذِينَ يَقُولُونَ لَا تُنْفِقُوا عَلَىٰ مَنْ عِنْدَ رَسُولِ اللَّهِ حَتَّىٰ يَنْفَضُّوا ۗ وَلِلَّهِ خَزَائِنُ السَّمَاوَاتِ وَالْأَرْضِ وَلَٰكِنَّ الْمُنَافِقِينَ لَا يَفْقَهُونَ
Awon ni awon t’o n wi pe: “Eyin ko gbodo na owo fun awon t’o wa lodo Ojise Allahu titi won yoo fi fonka. Ti Allahu si ni awon apoti-oro sanmo ati ile, sugbon awon sobe-selu musulumi ko nii gbo agboye
يَقُولُونَ لَئِنْ رَجَعْنَا إِلَى الْمَدِينَةِ لَيُخْرِجَنَّ الْأَعَزُّ مِنْهَا الْأَذَلَّ ۚ وَلِلَّهِ الْعِزَّةُ وَلِرَسُولِهِ وَلِلْمُؤْمِنِينَ وَلَٰكِنَّ الْمُنَافِقِينَ لَا يَعْلَمُونَ
Won n wi pe: “Dajudaju ti a ba pada de sinu ilu Modinah, nse ni awon alagbara (ilu) yoo yo awon eni yepere jade kuro ninu ilu." Agbara si n je ti Allahu, ati ti Ojise Re ati awon onigbagbo ododo, sugbon awon sobe-selu musulumi ko mo
يَا أَيُّهَا الَّذِينَ آمَنُوا لَا تُلْهِكُمْ أَمْوَالُكُمْ وَلَا أَوْلَادُكُمْ عَنْ ذِكْرِ اللَّهِ ۚ وَمَنْ يَفْعَلْ ذَٰلِكَ فَأُولَٰئِكَ هُمُ الْخَاسِرُونَ
Eyin ti e gbagbo ni ododo, e ma se je ki awon dukia yin ati awon omo yin ko airoju ba yin nibi iranti Allahu. Enikeni ti o ba ko sinu (airoju) yen, awon wonyen, awon ni eni ofo
وَأَنْفِقُوا مِنْ مَا رَزَقْنَاكُمْ مِنْ قَبْلِ أَنْ يَأْتِيَ أَحَدَكُمُ الْمَوْتُ فَيَقُولَ رَبِّ لَوْلَا أَخَّرْتَنِي إِلَىٰ أَجَلٍ قَرِيبٍ فَأَصَّدَّقَ وَأَكُنْ مِنَ الصَّالِحِينَ
E na ninu ohun ti A pese fun yin siwaju ki iku to de ba eni kan yin, ki o wa wi pe: "Oluwa mi, ki o si je pe O lo mi lara si i titi di igba kan to sunmo, emi iba si le maa tore, emi iba si wa lara awon eni rere
Load More