Surah Al-Qasas Translated in Yoruba
نَتْلُو عَلَيْكَ مِنْ نَبَإِ مُوسَىٰ وَفِرْعَوْنَ بِالْحَقِّ لِقَوْمٍ يُؤْمِنُونَ
A n ke ninu iro (Anabi) Musa ati Fir‘aon fun o pelu ododo nitori ijo t’o gbagbo lododo
إِنَّ فِرْعَوْنَ عَلَا فِي الْأَرْضِ وَجَعَلَ أَهْلَهَا شِيَعًا يَسْتَضْعِفُ طَائِفَةً مِنْهُمْ يُذَبِّحُ أَبْنَاءَهُمْ وَيَسْتَحْيِي نِسَاءَهُمْ ۚ إِنَّهُ كَانَ مِنَ الْمُفْسِدِينَ
Dajudaju Fir‘aon segberaga lori ile. O se awon eniyan re ni ijo-ijo. O n da igun kan ninu won lagara; o n pa awon omokunrin won, o si n da awon obinrin won si. Dajudaju o wa ninu awon obileje
وَنُرِيدُ أَنْ نَمُنَّ عَلَى الَّذِينَ اسْتُضْعِفُوا فِي الْأَرْضِ وَنَجْعَلَهُمْ أَئِمَّةً وَنَجْعَلَهُمُ الْوَارِثِينَ
A si fe sedera fun awon ti won foju tinrin lori ile, A (fe) se won ni asiwaju. A si (fe) ki won jogun (ile)
وَنُمَكِّنَ لَهُمْ فِي الْأَرْضِ وَنُرِيَ فِرْعَوْنَ وَهَامَانَ وَجُنُودَهُمَا مِنْهُمْ مَا كَانُوا يَحْذَرُونَ
A (fe) gba won laaye lori ile. Lati ara won, A si (fe) fi han Fir‘aon ati Hamon pelu awon omo ogun awon mejeeji ohun ti won n sora fun lara won
وَأَوْحَيْنَا إِلَىٰ أُمِّ مُوسَىٰ أَنْ أَرْضِعِيهِ ۖ فَإِذَا خِفْتِ عَلَيْهِ فَأَلْقِيهِ فِي الْيَمِّ وَلَا تَخَافِي وَلَا تَحْزَنِي ۖ إِنَّا رَادُّوهُ إِلَيْكِ وَجَاعِلُوهُ مِنَ الْمُرْسَلِينَ
A si ranse si iya (Anabi) Musa pe: “Fun un ni omu mu. Ti o ba si n paya lori re, ju u sinu agbami odo. Ma se beru. Ma si se banuje. Dajudaju Awa maa da a pada si odo re. A o si se e ni ara awon Ojise
فَالْتَقَطَهُ آلُ فِرْعَوْنَ لِيَكُونَ لَهُمْ عَدُوًّا وَحَزَنًا ۗ إِنَّ فِرْعَوْنَ وَهَامَانَ وَجُنُودَهُمَا كَانُوا خَاطِئِينَ
Nigba naa, awon eniyan Fir‘aon ri i he nitori ki o le je ota ati ibanuje fun won. Dajudaju Fir‘aon, Hamon ati awon omo ogun awon mejeeji, won je alasise
وَقَالَتِ امْرَأَتُ فِرْعَوْنَ قُرَّتُ عَيْنٍ لِي وَلَكَ ۖ لَا تَقْتُلُوهُ عَسَىٰ أَنْ يَنْفَعَنَا أَوْ نَتَّخِذَهُ وَلَدًا وَهُمْ لَا يَشْعُرُونَ
Iyawo Fir‘aon wi pe: “Itutu-oju ni (omo yii) fun emi ati iwo. E ma se pa a. O le je pe o maa se wa ni anfaani tabi ki a fi se omo.” Won ko si fura
وَأَصْبَحَ فُؤَادُ أُمِّ مُوسَىٰ فَارِغًا ۖ إِنْ كَادَتْ لَتُبْدِي بِهِ لَوْلَا أَنْ رَبَطْنَا عَلَىٰ قَلْبِهَا لِتَكُونَ مِنَ الْمُؤْمِنِينَ
Okan iya (Anabi) Musa pami (lori oro Musa, ko si ri nnkan miiran ro mo tayo re) o kuku fee safi han re (pe omo oun ni nigba ti won pe e de odo Fir‘aon) ti ko ba je pe A ki i lokan nitori ki o le wa ninu awon onigbagbo ododo
Load More