Surah An-Naml Translated in Yoruba
طس ۚ تِلْكَ آيَاتُ الْقُرْآنِ وَكِتَابٍ مُبِينٍ
To sin. Iwonyi ni awon ayah al-Ƙur’an ati (awon ayah) Tira t’o n yanju oro eda
الَّذِينَ يُقِيمُونَ الصَّلَاةَ وَيُؤْتُونَ الزَّكَاةَ وَهُمْ بِالْآخِرَةِ هُمْ يُوقِنُونَ
awon t’o n kirun, ti won n yo zakah. Awon si ni won ni amodaju nipa Ojo Ikeyin
إِنَّ الَّذِينَ لَا يُؤْمِنُونَ بِالْآخِرَةِ زَيَّنَّا لَهُمْ أَعْمَالَهُمْ فَهُمْ يَعْمَهُونَ
Dajudaju awon ti ko gba Ojo Ikeyin gbo, A ti se awon ise (aburu owo) won ni oso fun won, Nitori naa, won yo si maa pa ridarida
أُولَٰئِكَ الَّذِينَ لَهُمْ سُوءُ الْعَذَابِ وَهُمْ فِي الْآخِرَةِ هُمُ الْأَخْسَرُونَ
Awon wonyen ni awon ti iya buruku wa fun. Awon si ni eni ofo julo ni Ojo Ikeyin
وَإِنَّكَ لَتُلَقَّى الْقُرْآنَ مِنْ لَدُنْ حَكِيمٍ عَلِيمٍ
Dajudaju o n gba al-Ƙur’an lati odo Ologbon, Onimo
إِذْ قَالَ مُوسَىٰ لِأَهْلِهِ إِنِّي آنَسْتُ نَارًا سَآتِيكُمْ مِنْهَا بِخَبَرٍ أَوْ آتِيكُمْ بِشِهَابٍ قَبَسٍ لَعَلَّكُمْ تَصْطَلُونَ
(Ranti) nigba ti (Anabi) Musa so fun awon eniyan re pe: “Dajudaju mo ri ina kan. Mo si maa lo mu iro kan wa fun yin lati ibe, tabi ki ng mu ogunna kan t’o n tanna wa fun yin nitori ki e le yena
فَلَمَّا جَاءَهَا نُودِيَ أَنْ بُورِكَ مَنْ فِي النَّارِ وَمَنْ حَوْلَهَا وَسُبْحَانَ اللَّهِ رَبِّ الْعَالَمِينَ
Nigba ti o de ibe, A pepe pe ki ibukun maa be fun eni ti o wa nibi ina naa ati eni ti o wa ni ayika re. Mimo si ni fun Allahu, Oluwa gbogbo eda
يَا مُوسَىٰ إِنَّهُ أَنَا اللَّهُ الْعَزِيزُ الْحَكِيمُ
Musa, dajudaju Emi ni Allahu, Alagbara, Ologbon
وَأَلْقِ عَصَاكَ ۚ فَلَمَّا رَآهَا تَهْتَزُّ كَأَنَّهَا جَانٌّ وَلَّىٰ مُدْبِرًا وَلَمْ يُعَقِّبْ ۚ يَا مُوسَىٰ لَا تَخَفْ إِنِّي لَا يَخَافُ لَدَيَّ الْمُرْسَلُونَ
Ju opa re sile. (O si se bee.) Amo nigba ti o ri i t’o n yira pada bi eni pe ejo ni, Musa peyin da, o n sa lo. Ko si pada. (Allahu so pe:) Musa, ma se paya. Dajudaju awon Ojise ki i paya lodo Mi
Load More