Surah An-Nisa Translated in Yoruba
يَا أَيُّهَا النَّاسُ اتَّقُوا رَبَّكُمُ الَّذِي خَلَقَكُمْ مِنْ نَفْسٍ وَاحِدَةٍ وَخَلَقَ مِنْهَا زَوْجَهَا وَبَثَّ مِنْهُمَا رِجَالًا كَثِيرًا وَنِسَاءً ۚ وَاتَّقُوا اللَّهَ الَّذِي تَسَاءَلُونَ بِهِ وَالْأَرْحَامَ ۚ إِنَّ اللَّهَ كَانَ عَلَيْكُمْ رَقِيبًا
Eyin eniyan, e beru Oluwa yin, Eni ti O seda yin lati ara emi eyo kan (iyen, Anabi Adam). O si seda aya re (Hawa’) lati ara re. O fon opolopo okunrin ati obinrin jade lati ara awon mejeeji. Ki e si beru Allahu, Eni ti e n fi be ara yin. (E so) okun-ibi. Dajudaju Allahu n je Oluso lori yin
وَآتُوا الْيَتَامَىٰ أَمْوَالَهُمْ ۖ وَلَا تَتَبَدَّلُوا الْخَبِيثَ بِالطَّيِّبِ ۖ وَلَا تَأْكُلُوا أَمْوَالَهُمْ إِلَىٰ أَمْوَالِكُمْ ۚ إِنَّهُ كَانَ حُوبًا كَبِيرًا
E fun awon omo orukan ni dukia won. E ma se fi nnkan buruku paaro nnkan daadaa. E si ma se je dukia won mo dukia yin; dajudaju o je ese nla
وَإِنْ خِفْتُمْ أَلَّا تُقْسِطُوا فِي الْيَتَامَىٰ فَانْكِحُوا مَا طَابَ لَكُمْ مِنَ النِّسَاءِ مَثْنَىٰ وَثُلَاثَ وَرُبَاعَ ۖ فَإِنْ خِفْتُمْ أَلَّا تَعْدِلُوا فَوَاحِدَةً أَوْ مَا مَلَكَتْ أَيْمَانُكُمْ ۚ ذَٰلِكَ أَدْنَىٰ أَلَّا تَعُولُوا
Ti e ba paya pe e o nii se deede nipa (fife) omo orukan, e fe eni t’o letoo si yin ninu awon obinrin; meji tabi meta tabi merin. Sugbon ti e ba paya pe e o nii se deede, (e fe) eyo kan tabi erubinrin yin. Iyen sunmo julo pe e o nii sabosi
وَآتُوا النِّسَاءَ صَدُقَاتِهِنَّ نِحْلَةً ۚ فَإِنْ طِبْنَ لَكُمْ عَنْ شَيْءٍ مِنْهُ نَفْسًا فَكُلُوهُ هَنِيئًا مَرِيئًا
E fun awon obinrin ni sodaaki won ni tokan-tokan. Ti won ba si fi inu didun yonda kini kan fun yin ninu re, e je e pelu irorun ati igbadun
وَلَا تُؤْتُوا السُّفَهَاءَ أَمْوَالَكُمُ الَّتِي جَعَلَ اللَّهُ لَكُمْ قِيَامًا وَارْزُقُوهُمْ فِيهَا وَاكْسُوهُمْ وَقُولُوا لَهُمْ قَوْلًا مَعْرُوفًا
E ma se ko dukia yin ti Allahu fi se gbemiiro fun yin le awon alailoye lowo. E pese ije-imu fun won ninu re, ki e si raso fun won. Ki e si maa soro daadaa fun won
وَابْتَلُوا الْيَتَامَىٰ حَتَّىٰ إِذَا بَلَغُوا النِّكَاحَ فَإِنْ آنَسْتُمْ مِنْهُمْ رُشْدًا فَادْفَعُوا إِلَيْهِمْ أَمْوَالَهُمْ ۖ وَلَا تَأْكُلُوهَا إِسْرَافًا وَبِدَارًا أَنْ يَكْبَرُوا ۚ وَمَنْ كَانَ غَنِيًّا فَلْيَسْتَعْفِفْ ۖ وَمَنْ كَانَ فَقِيرًا فَلْيَأْكُلْ بِالْمَعْرُوفِ ۚ فَإِذَا دَفَعْتُمْ إِلَيْهِمْ أَمْوَالَهُمْ فَأَشْهِدُوا عَلَيْهِمْ ۚ وَكَفَىٰ بِاللَّهِ حَسِيبًا
E maa sagbeyewo (oye) awon omo orukan titi won yoo fi to igbeyawo se. Ti e ba si ti ri oye lara won, ki e da dukia won pada fun won. E o gbodo je dukia won ni ije apa ati ijekuje ki won to dagba. Eni ti o ba je oloro, ki o moju kuro (nibe). Eni ti o ba je alaini, ki o je ninu re ni ona t’o dara. Nitori naa, ti e ba fe da dukia won pada fun won, e pe awon elerii si won. Allahu si to ni Olusiro
لِلرِّجَالِ نَصِيبٌ مِمَّا تَرَكَ الْوَالِدَانِ وَالْأَقْرَبُونَ وَلِلنِّسَاءِ نَصِيبٌ مِمَّا تَرَكَ الْوَالِدَانِ وَالْأَقْرَبُونَ مِمَّا قَلَّ مِنْهُ أَوْ كَثُرَ ۚ نَصِيبًا مَفْرُوضًا
Awon okunrin ni ipin ninu ohun ti obi mejeeji ati ebi fi sile. Ati pe awon obinrin naa ni ipin ninu ohun ti obi mejeeji ati ebi fi sile. Ninu ohun t’o kere ninu re tabi t’o po; (o je) ipin ti won ti pin (fun won)
وَإِذَا حَضَرَ الْقِسْمَةَ أُولُو الْقُرْبَىٰ وَالْيَتَامَىٰ وَالْمَسَاكِينُ فَارْزُقُوهُمْ مِنْهُ وَقُولُوا لَهُمْ قَوْلًا مَعْرُوفًا
Nigba ti awon ebi, awon omo orukan ati awon mekunnu ba wa ni (ijokoo) ogun pipin, e fun won ninu re (siwaju ki e to pin ogun), ki e si soro daadaa fun won
وَلْيَخْشَ الَّذِينَ لَوْ تَرَكُوا مِنْ خَلْفِهِمْ ذُرِّيَّةً ضِعَافًا خَافُوا عَلَيْهِمْ فَلْيَتَّقُوا اللَّهَ وَلْيَقُولُوا قَوْلًا سَدِيدًا
Awon (olupingun ati alagbawo omo orukan) ti o ba je pe awon naa maa fi omo wewe sile, ti won si n paya lori won, ki won yaa beru Allahu. Ki won si maa soro daadaa (fun omo orukan)
إِنَّ الَّذِينَ يَأْكُلُونَ أَمْوَالَ الْيَتَامَىٰ ظُلْمًا إِنَّمَا يَأْكُلُونَ فِي بُطُونِهِمْ نَارًا ۖ وَسَيَصْلَوْنَ سَعِيرًا
Dajudaju awon t’o n je dukia omo orukan pelu abosi, Ina kuku ni won n je sinu ikun won. Won si maa wo inu Ina t’o n jo
Load More