Surah Ar-Rad Translated in Yoruba
المر ۚ تِلْكَ آيَاتُ الْكِتَابِ ۗ وَالَّذِي أُنْزِلَ إِلَيْكَ مِنْ رَبِّكَ الْحَقُّ وَلَٰكِنَّ أَكْثَرَ النَّاسِ لَا يُؤْمِنُونَ
’Alif lam mim ro. Iwonyi ni awon ayah Tira naa. Ati pe ododo ni ohun ti won sokale fun o lati odo Oluwa re, sugbon opolopo awon eniyan ko gbagbo
اللَّهُ الَّذِي رَفَعَ السَّمَاوَاتِ بِغَيْرِ عَمَدٍ تَرَوْنَهَا ۖ ثُمَّ اسْتَوَىٰ عَلَى الْعَرْشِ ۖ وَسَخَّرَ الشَّمْسَ وَالْقَمَرَ ۖ كُلٌّ يَجْرِي لِأَجَلٍ مُسَمًّى ۚ يُدَبِّرُ الْأَمْرَ يُفَصِّلُ الْآيَاتِ لَعَلَّكُمْ بِلِقَاءِ رَبِّكُمْ تُوقِنُونَ
Allahu ni Eni ti O gbe awon sanmo ga soke lai si awon opo kan (fun un) ti e le foju ri. Leyin naa, O gunwa sori Ite-ola. O ro oorun ati osupa; ikookan won n rin fun gbedeke akoko kan. O n se eto oro (eda). O n se alaye awon ayah nitori ki e le mo amodaju nipa ipade Oluwa yin
وَهُوَ الَّذِي مَدَّ الْأَرْضَ وَجَعَلَ فِيهَا رَوَاسِيَ وَأَنْهَارًا ۖ وَمِنْ كُلِّ الثَّمَرَاتِ جَعَلَ فِيهَا زَوْجَيْنِ اثْنَيْنِ ۖ يُغْشِي اللَّيْلَ النَّهَارَ ۚ إِنَّ فِي ذَٰلِكَ لَآيَاتٍ لِقَوْمٍ يَتَفَكَّرُونَ
Oun ni Eni ti O te ile perese. O si fi awon apata t’o duro gbagidi sinu ile ati awon odo. Ati pe ninu gbogbo awon eso, O se e ni orisi meji-meji. O n fi oru bo osan loju. Dajudaju awon ami wa ninu iyen fun ijo t’o ni arojinle
وَفِي الْأَرْضِ قِطَعٌ مُتَجَاوِرَاتٌ وَجَنَّاتٌ مِنْ أَعْنَابٍ وَزَرْعٌ وَنَخِيلٌ صِنْوَانٌ وَغَيْرُ صِنْوَانٍ يُسْقَىٰ بِمَاءٍ وَاحِدٍ وَنُفَضِّلُ بَعْضَهَا عَلَىٰ بَعْضٍ فِي الْأُكُلِ ۚ إِنَّ فِي ذَٰلِكَ لَآيَاتٍ لِقَوْمٍ يَعْقِلُونَ
O tun wa ninu ile awon abala-abala ile (oniran-anran) t’o wa nitosi ara won ati awon ogba oko ajara, irugbin ati igi dabinu t’o peka ati eyi ti ko peka, ti won n fi omi eyo kan won. (Sibesibe) A se ajulo fun apa kan re lori apa kan nibi jije. Dajudaju awon ami wa ninu iyen fun ijo t’o ni laakaye
وَإِنْ تَعْجَبْ فَعَجَبٌ قَوْلُهُمْ أَإِذَا كُنَّا تُرَابًا أَإِنَّا لَفِي خَلْقٍ جَدِيدٍ ۗ أُولَٰئِكَ الَّذِينَ كَفَرُوا بِرَبِّهِمْ ۖ وَأُولَٰئِكَ الْأَغْلَالُ فِي أَعْنَاقِهِمْ ۖ وَأُولَٰئِكَ أَصْحَابُ النَّارِ ۖ هُمْ فِيهَا خَالِدُونَ
Ti o ba seemo, eemo ma ni oro (enu) won (nipa bi won se so pe): “Se nigba ti a ba ti di erupe tan, se nigba naa ni awa yoo tun di eda titun?” Awon wonyen ni awon t’o sai gbagbo ninu Oluwa won. Awon wonyen ni ewon n be lorun won. Awon wonyen si ni ero inu Ina. Olusegbere ni won ninu re
وَيَسْتَعْجِلُونَكَ بِالسَّيِّئَةِ قَبْلَ الْحَسَنَةِ وَقَدْ خَلَتْ مِنْ قَبْلِهِمُ الْمَثُلَاتُ ۗ وَإِنَّ رَبَّكَ لَذُو مَغْفِرَةٍ لِلنَّاسِ عَلَىٰ ظُلْمِهِمْ ۖ وَإِنَّ رَبَّكَ لَشَدِيدُ الْعِقَابِ
Won tun n kan o loju pe ki aburu sele siwaju rere. Awon apeere iya kuku ti sele siwaju won. Ati pe dajudaju Oluwa re ni Alaforijin fun awon eniyan lori abosi (owo) won. Dajudaju Oluwa re le nibi iya
وَيَقُولُ الَّذِينَ كَفَرُوا لَوْلَا أُنْزِلَ عَلَيْهِ آيَةٌ مِنْ رَبِّهِ ۗ إِنَّمَا أَنْتَ مُنْذِرٌ ۖ وَلِكُلِّ قَوْمٍ هَادٍ
Awon t’o sai gbagbo n wi pe: “Ki ni ko je ki Won so ami kan kale fun un lati odo Oluwa re?” Olukilo ma ni iwo. Olutosona si wa fun ijo kookan
اللَّهُ يَعْلَمُ مَا تَحْمِلُ كُلُّ أُنْثَىٰ وَمَا تَغِيضُ الْأَرْحَامُ وَمَا تَزْدَادُ ۖ وَكُلُّ شَيْءٍ عِنْدَهُ بِمِقْدَارٍ
Allahu mo ohun ti obinrin kookan ni loyun ati ohun ti ile omo yoo fi din ku (ninu ojo ibimo) ati ohun ti o maa fi lekun. Nnkan kookan l’o si ni odiwon lodo Re
عَالِمُ الْغَيْبِ وَالشَّهَادَةِ الْكَبِيرُ الْمُتَعَالِ
(Allahu ni) Onimo-ikoko-ati- gbangba. O tobi, O ga
سَوَاءٌ مِنْكُمْ مَنْ أَسَرَّ الْقَوْلَ وَمَنْ جَهَرَ بِهِ وَمَنْ هُوَ مُسْتَخْفٍ بِاللَّيْلِ وَسَارِبٌ بِالنَّهَارِ
Bakan naa ni (lodo Allahu), eni ti o fi oro pamo sinu ninu yin ati eni ti o so o sita pelu eni ti o fi oru boju ati eni ti o n rin kiri ni osan
Load More