Quran Apps in many lanuages:

Surah As-Saaffat Translated in Yoruba

وَالصَّافَّاتِ صَفًّا
(Allahu bura pelu) awon molaika oluto-lowoowo taara
فَالزَّاجِرَاتِ زَجْرًا
ati awon molaika t’o n wo esujo kiri taara
فَالتَّالِيَاتِ ذِكْرًا
ati awon molaika onke-tira iranti
إِنَّ إِلَٰهَكُمْ لَوَاحِدٌ
Dajudaju Olohun yin, Okan soso ni
رَبُّ السَّمَاوَاتِ وَالْأَرْضِ وَمَا بَيْنَهُمَا وَرَبُّ الْمَشَارِقِ
Oluwa awon sanmo ati ile ati ohunkohun ti n be laaarin awon mejeeji. Oun si ni Oluwa awon ibuyo oorun
إِنَّا زَيَّنَّا السَّمَاءَ الدُّنْيَا بِزِينَةٍ الْكَوَاكِبِ
Dajudaju Awa fi awon irawo se sanmo ile aye ni oso
وَحِفْظًا مِنْ كُلِّ شَيْطَانٍ مَارِدٍ
ati iso nibi (aburu) gbogbo esu olorikunkun
لَا يَسَّمَّعُونَ إِلَى الْمَلَإِ الْأَعْلَىٰ وَيُقْذَفُونَ مِنْ كُلِّ جَانِبٍ
(Awon esu) ko si nii le teti si ijo (molaika t’o wa ni) aye giga julo (ninu sanmo). (Awon molaika) yo si maa ku (awon esu) loko (eta irawo) ni gbogbo agbegbe (sanmo)
دُحُورًا ۖ وَلَهُمْ عَذَابٌ وَاصِبٌ
Won n le won danu. Iya ailopin si wa fun won
إِلَّا مَنْ خَطِفَ الْخَطْفَةَ فَأَتْبَعَهُ شِهَابٌ ثَاقِبٌ
(Won ko nii gbo oro ni kikun) ayafi eni ti o ba ri oro ajigbo gbe, nigba naa (ni molaika) yo si fi eta irawo ina t’o maa jo o tele e
Load More