Quran Apps in many lanuages:

Surah As-Saff Translated in Yoruba

سَبَّحَ لِلَّهِ مَا فِي السَّمَاوَاتِ وَمَا فِي الْأَرْضِ ۖ وَهُوَ الْعَزِيزُ الْحَكِيمُ
Ohunkohun t’o wa ninu awon sanmo ati ohunkohun t’o wa ninu ile n safomo fun Allahu. Oun si ni Alagbara, Ologbon
يَا أَيُّهَا الَّذِينَ آمَنُوا لِمَ تَقُولُونَ مَا لَا تَفْعَلُونَ
Eyin ti e gbagbo ni ododo, nitori ki ni e se n so ohun ti e o nii se nise
كَبُرَ مَقْتًا عِنْدَ اللَّهِ أَنْ تَقُولُوا مَا لَا تَفْعَلُونَ
O je ohun ibinu t’o tobi ni odo Allahu pe ki e so ohun ti e o nii se
إِنَّ اللَّهَ يُحِبُّ الَّذِينَ يُقَاتِلُونَ فِي سَبِيلِهِ صَفًّا كَأَنَّهُمْ بُنْيَانٌ مَرْصُوصٌ
Dajudaju Allahu feran awon t’o n jagun fun esin Re (ti won to ni) owoowo bi eni pe ogiri ile ti won le po mora won ni won
وَإِذْ قَالَ مُوسَىٰ لِقَوْمِهِ يَا قَوْمِ لِمَ تُؤْذُونَنِي وَقَدْ تَعْلَمُونَ أَنِّي رَسُولُ اللَّهِ إِلَيْكُمْ ۖ فَلَمَّا زَاغُوا أَزَاغَ اللَّهُ قُلُوبَهُمْ ۚ وَاللَّهُ لَا يَهْدِي الْقَوْمَ الْفَاسِقِينَ
(Ranti) nigba ti (Anabi) Musa so fun ijo re pe: "Eyin ijo mi, nitori ki ni e oo se fi inira kan mi. E si kuku mo pe dajudaju Ojise Allahu ni emi je si yin." Nigba ti won si ye (kuro nibi ododo), Allahu ye okan won. Allahu ko si nii fi ona mo ijo obileje
وَإِذْ قَالَ عِيسَى ابْنُ مَرْيَمَ يَا بَنِي إِسْرَائِيلَ إِنِّي رَسُولُ اللَّهِ إِلَيْكُمْ مُصَدِّقًا لِمَا بَيْنَ يَدَيَّ مِنَ التَّوْرَاةِ وَمُبَشِّرًا بِرَسُولٍ يَأْتِي مِنْ بَعْدِي اسْمُهُ أَحْمَدُ ۖ فَلَمَّا جَاءَهُمْ بِالْبَيِّنَاتِ قَالُوا هَٰذَا سِحْرٌ مُبِينٌ
(Ranti) nigba ti ‘Isa omo Moryam so pe: "Eyin omo ’Isro’il, dajudaju emi ni Ojise Allahu si yin. Mo n fi ohun t’o je ododo rinle nipa eyi t’o siwaju mi ninu Taorah. Mo si n mu iro-idunnu wa nipa Ojise kan t’o n bo leyin mi. Oruko re ni ’Ahmod." Nigba ti o ba si wa ba won pelu awon eri t’o yanju, won a wi pe: "Idan ponnbele ni eyi
وَمَنْ أَظْلَمُ مِمَّنِ افْتَرَىٰ عَلَى اللَّهِ الْكَذِبَ وَهُوَ يُدْعَىٰ إِلَى الْإِسْلَامِ ۚ وَاللَّهُ لَا يَهْدِي الْقَوْمَ الظَّالِمِينَ
Ta si ni o sabosi t’o tayo eni ti o da adapa iro mo Allahu, ti won si n pe e sinu ’Islam! Allahu ko si nii fi ona mo ijo alabosi
يُرِيدُونَ لِيُطْفِئُوا نُورَ اللَّهِ بِأَفْوَاهِهِمْ وَاللَّهُ مُتِمُّ نُورِهِ وَلَوْ كَرِهَ الْكَافِرُونَ
Won n gbero lati fi (oro) enu won pa imole Allahu. Allahu yo si mu imole Re tan kari, awon alaigbagbo ibaa korira re
هُوَ الَّذِي أَرْسَلَ رَسُولَهُ بِالْهُدَىٰ وَدِينِ الْحَقِّ لِيُظْهِرَهُ عَلَى الدِّينِ كُلِّهِ وَلَوْ كَرِهَ الْمُشْرِكُونَ
(Allahu) Oun ni Eni ti O fi imona ati esin ododo (’Islam) ran Ojise Re nitori ki O le fi bori esin (miiran), gbogbo re patapata, awon osebo ibaa korira re
يَا أَيُّهَا الَّذِينَ آمَنُوا هَلْ أَدُلُّكُمْ عَلَىٰ تِجَارَةٍ تُنْجِيكُمْ مِنْ عَذَابٍ أَلِيمٍ
Eyin ti e gbagbo ni ododo, se ki Ng toka yin si okowo kan ti o maa gba yin la ninu iya eleta-elero
Load More