Quran Apps in many lanuages:

Surah As-Sajda Translated in Yoruba

الم
’Alif lam mim
تَنْزِيلُ الْكِتَابِ لَا رَيْبَ فِيهِ مِنْ رَبِّ الْعَالَمِينَ
Isokale Tira naa, ko si iyemeji ninu re (pe o wa) lati odo Oluwa gbogbo eda
أَمْ يَقُولُونَ افْتَرَاهُ ۚ بَلْ هُوَ الْحَقُّ مِنْ رَبِّكَ لِتُنْذِرَ قَوْمًا مَا أَتَاهُمْ مِنْ نَذِيرٍ مِنْ قَبْلِكَ لَعَلَّهُمْ يَهْتَدُونَ
Tabi won n wi pe: “O da adapa iro re ni.” Rara o! Ododo ni lati odo Oluwa re nitori ki o le fi sekilo fun awon eniyan kan, ti olukilo kan ko wa ba won ri siwaju re, nitori ki won le mona
اللَّهُ الَّذِي خَلَقَ السَّمَاوَاتِ وَالْأَرْضَ وَمَا بَيْنَهُمَا فِي سِتَّةِ أَيَّامٍ ثُمَّ اسْتَوَىٰ عَلَى الْعَرْشِ ۖ مَا لَكُمْ مِنْ دُونِهِ مِنْ وَلِيٍّ وَلَا شَفِيعٍ ۚ أَفَلَا تَتَذَكَّرُونَ
Allahu ni Eni ti O seda awon sanmo, ile ati nnkan t’o wa laaarin mejeeji laaarin ojo mefa. Leyin naa, O gunwa sori Ite-ola. Ko si alaabo ati olusipe kan fun yin leyin Re. Se e o nii lo iranti ni
يُدَبِّرُ الْأَمْرَ مِنَ السَّمَاءِ إِلَى الْأَرْضِ ثُمَّ يَعْرُجُ إِلَيْهِ فِي يَوْمٍ كَانَ مِقْدَارُهُ أَلْفَ سَنَةٍ مِمَّا تَعُدُّونَ
O n seto oro (eda) lati sanmo wa sori ile. Leyin naa, (abo oro eda) yoo gunke to O lo laaarin ojo kan ti odiwon re to egberun odun ninu onka ti e n ka
ذَٰلِكَ عَالِمُ الْغَيْبِ وَالشَّهَادَةِ الْعَزِيزُ الرَّحِيمُ
Iyen ni Onimo-ikoko ati gbangba, Alagbara, Asake-orun
الَّذِي أَحْسَنَ كُلَّ شَيْءٍ خَلَقَهُ ۖ وَبَدَأَ خَلْقَ الْإِنْسَانِ مِنْ طِينٍ
Eni t’o se gbogbo nnkan ti O da ni daadaa. O si bere iseda eniyan lati inu erupe amo
ثُمَّ جَعَلَ نَسْلَهُ مِنْ سُلَالَةٍ مِنْ مَاءٍ مَهِينٍ
Leyin naa, O se awon aromodomo re lati ara ohun ti A mu jade lati ara omi lile yepere
ثُمَّ سَوَّاهُ وَنَفَخَ فِيهِ مِنْ رُوحِهِ ۖ وَجَعَلَ لَكُمُ السَّمْعَ وَالْأَبْصَارَ وَالْأَفْئِدَةَ ۚ قَلِيلًا مَا تَشْكُرُونَ
Leyin naa, O to (orikeerikee) re dogba. O si fe (emi) si i lara ninu emi Re (ti O da). O tun se igboro, iriran ati okan fun yin. Die ni ope ti e n da
وَقَالُوا أَإِذَا ضَلَلْنَا فِي الْأَرْضِ أَإِنَّا لَفِي خَلْقٍ جَدِيدٍ ۚ بَلْ هُمْ بِلِقَاءِ رَبِّهِمْ كَافِرُونَ
Won si wi pe: “Nje nigba ti a ba ti poora sinu ile, nje awa tun le wa ni eda titun mo? Ani se, awon ni alaigbagbo ninu ipade Oluwa won
Load More