Surah Ash-Shura Translated in Yoruba
كَذَٰلِكَ يُوحِي إِلَيْكَ وَإِلَى الَّذِينَ مِنْ قَبْلِكَ اللَّهُ الْعَزِيزُ الْحَكِيمُ
Bayen ni Allahu, Alagbara, Ologbon se n fi imisi ranse si iwo ati awon t’o siwaju re
لَهُ مَا فِي السَّمَاوَاتِ وَمَا فِي الْأَرْضِ ۖ وَهُوَ الْعَلِيُّ الْعَظِيمُ
TiRe ni ohunkohun t’o wa ninu awon sanmo ati ohunkohun t’o wa ninu ile. O ga, O tobi
تَكَادُ السَّمَاوَاتُ يَتَفَطَّرْنَ مِنْ فَوْقِهِنَّ ۚ وَالْمَلَائِكَةُ يُسَبِّحُونَ بِحَمْدِ رَبِّهِمْ وَيَسْتَغْفِرُونَ لِمَنْ فِي الْأَرْضِ ۗ أَلَا إِنَّ اللَّهَ هُوَ الْغَفُورُ الرَّحِيمُ
Sanmo fee faya lati oke won (nipa titobi Allahu). Awon molaika si n se afomo pelu idupe fun Oluwa won. Won si n toro aforijin fun awon t’o wa lori ile. Gbo Mi, dajudaju Allahu, Oun ni Alaforijin, Asake-orun
وَالَّذِينَ اتَّخَذُوا مِنْ دُونِهِ أَوْلِيَاءَ اللَّهُ حَفِيظٌ عَلَيْهِمْ وَمَا أَنْتَ عَلَيْهِمْ بِوَكِيلٍ
Awon t’o mu awon alatileyin kan leyin Re, Allahu si ni Alaabo lori won. Iwo si ko ni oluso lori won
وَكَذَٰلِكَ أَوْحَيْنَا إِلَيْكَ قُرْآنًا عَرَبِيًّا لِتُنْذِرَ أُمَّ الْقُرَىٰ وَمَنْ حَوْلَهَا وَتُنْذِرَ يَوْمَ الْجَمْعِ لَا رَيْبَ فِيهِ ۚ فَرِيقٌ فِي الْجَنَّةِ وَفَرِيقٌ فِي السَّعِيرِ
Bayen ni A se fi al-Ƙur’an ranse si o ni ede Larubawa nitori ki o le fi se ikilo fun ’Ummul-Ƙuro (iyen, ara ilu Mokkah) ati enikeni ti o ba wa ni ayika re (iyen, ara ilu yooku), ati nitori ki o le fi se ikilo nipa Ojo Akojo, ti ko si iyemeji ninu re. Ijo kan yoo wa ninu Ogba Idera. Ijo kan yo si wa ninu Ina t’o n jo
وَلَوْ شَاءَ اللَّهُ لَجَعَلَهُمْ أُمَّةً وَاحِدَةً وَلَٰكِنْ يُدْخِلُ مَنْ يَشَاءُ فِي رَحْمَتِهِ ۚ وَالظَّالِمُونَ مَا لَهُمْ مِنْ وَلِيٍّ وَلَا نَصِيرٍ
Ti o ba je pe Allahu ba fe, iba se won ni ijo elesin eyo kan. Sugbon O n fi eni ti O ba fe sinu ike Re. Awon alabosi, ko si nii si alaabo ati alaranse kan fun won
أَمِ اتَّخَذُوا مِنْ دُونِهِ أَوْلِيَاءَ ۖ فَاللَّهُ هُوَ الْوَلِيُّ وَهُوَ يُحْيِي الْمَوْتَىٰ وَهُوَ عَلَىٰ كُلِّ شَيْءٍ قَدِيرٌ
Se won mu awon alaabo kan leyin Re ni? Allahu, Oun si ni Alaabo. Oun l’O n so awon oku di alaaye. Oun si ni Alagbara lori gbogbo nnkan
وَمَا اخْتَلَفْتُمْ فِيهِ مِنْ شَيْءٍ فَحُكْمُهُ إِلَى اللَّهِ ۚ ذَٰلِكُمُ اللَّهُ رَبِّي عَلَيْهِ تَوَكَّلْتُ وَإِلَيْهِ أُنِيبُ
Ohunkohun ti e ba yapa enu nipa re, idajo re di odo Allahu. Iyen ni Allahu, Oluwa mi. Oun ni mo gbarale. Odo Re si ni mo maa seri pada si (ni ti ironupiwada). oro Allahu ati idajo Re. Pelu agboye yii ayah yii je okan ninu awon ayah t’o n pa wa lase lati fi al-Ƙur’an ati sunnah Anabi (sollalahu alayhi wa sallam) yanju awon oro iyapa-enu
Load More