Surah At-Taghabun Translated in Yoruba
يُسَبِّحُ لِلَّهِ مَا فِي السَّمَاوَاتِ وَمَا فِي الْأَرْضِ ۖ لَهُ الْمُلْكُ وَلَهُ الْحَمْدُ ۖ وَهُوَ عَلَىٰ كُلِّ شَيْءٍ قَدِيرٌ
Ohunkohun t’o wa ninu awon sanmo ati ohunkohun t’o wa ninu ile n se afomo fun Allahu. TiRe ni ijoba. TiRe si ni ope. Oun si ni Alagbara lori gbogbo nnkan
هُوَ الَّذِي خَلَقَكُمْ فَمِنْكُمْ كَافِرٌ وَمِنْكُمْ مُؤْمِنٌ ۚ وَاللَّهُ بِمَا تَعْمَلُونَ بَصِيرٌ
Oun ni Eni ti O seda yin. Alaigbagbo wa ninu yin. Onigbagbo ododo si wa ninu yin. Allahu si ni Oluriran nipa ohun ti e n se
خَلَقَ السَّمَاوَاتِ وَالْأَرْضَ بِالْحَقِّ وَصَوَّرَكُمْ فَأَحْسَنَ صُوَرَكُمْ ۖ وَإِلَيْهِ الْمَصِيرُ
O seda awon sanmo ati ile pelu ododo. O ya aworan yin. O si se awon aworan yin daradara. Odo Re si ni abo eda
يَعْلَمُ مَا فِي السَّمَاوَاتِ وَالْأَرْضِ وَيَعْلَمُ مَا تُسِرُّونَ وَمَا تُعْلِنُونَ ۚ وَاللَّهُ عَلِيمٌ بِذَاتِ الصُّدُورِ
O mo ohunkohun t’o wa ninu awon sanmo ati ile. O si mo ohun ti e n fi pamo ati ohun ti e n safi han re. Allahu si ni Onimo nipa ohun t’o wa ninu igba-aya eda
أَلَمْ يَأْتِكُمْ نَبَأُ الَّذِينَ كَفَرُوا مِنْ قَبْلُ فَذَاقُوا وَبَالَ أَمْرِهِمْ وَلَهُمْ عَذَابٌ أَلِيمٌ
Se iro awon t’o sai gbagbo ni isaaju ko ti i de ba yin ni? Nitori naa, won to iya oran won wo. Iya eleta-elero si wa fun won
ذَٰلِكَ بِأَنَّهُ كَانَتْ تَأْتِيهِمْ رُسُلُهُمْ بِالْبَيِّنَاتِ فَقَالُوا أَبَشَرٌ يَهْدُونَنَا فَكَفَرُوا وَتَوَلَّوْا ۚ وَاسْتَغْنَى اللَّهُ ۚ وَاللَّهُ غَنِيٌّ حَمِيدٌ
Iyen nitori pe dajudaju awon Ojise won n wa ba won pelu awon eri t’o yanju. Won si wi pe: "Se abara l’o maa fi ona mo wa?" Nitori naa, won sai gbagbo. Won si peyin da (si ododo). Allahu si roro lai si awon. Ati pe Allahu ni Oloro, Olope
زَعَمَ الَّذِينَ كَفَرُوا أَنْ لَنْ يُبْعَثُوا ۚ قُلْ بَلَىٰ وَرَبِّي لَتُبْعَثُنَّ ثُمَّ لَتُنَبَّؤُنَّ بِمَا عَمِلْتُمْ ۚ وَذَٰلِكَ عَلَى اللَّهِ يَسِيرٌ
Awon t’o sai gbagbo lero pe A o nii gbe won dide. So pe: "Bee ko, mo fi Oluwa mi bura, dajudaju Won yoo gbe yin dide. Leyin naa, Won yoo fun yin ni iro ohun ti e se nise. Iyen si je irorun fun Allahu
فَآمِنُوا بِاللَّهِ وَرَسُولِهِ وَالنُّورِ الَّذِي أَنْزَلْنَا ۚ وَاللَّهُ بِمَا تَعْمَلُونَ خَبِيرٌ
Nitori naa, e gbagbo ninu Allahu ati Ojise Re ati imole ti A sokale. Allahu si ni Alamotan nipa ohun ti e n se
يَوْمَ يَجْمَعُكُمْ لِيَوْمِ الْجَمْعِ ۖ ذَٰلِكَ يَوْمُ التَّغَابُنِ ۗ وَمَنْ يُؤْمِنْ بِاللَّهِ وَيَعْمَلْ صَالِحًا يُكَفِّرْ عَنْهُ سَيِّئَاتِهِ وَيُدْخِلْهُ جَنَّاتٍ تَجْرِي مِنْ تَحْتِهَا الْأَنْهَارُ خَالِدِينَ فِيهَا أَبَدًا ۚ ذَٰلِكَ الْفَوْزُ الْعَظِيمُ
Ni ojo ti (Allahu) yoo ko yin jo fun ojo akojo. Iyen ni ojo ere ati adanu. Enikeni ti o ba gba Allahu gbo ni ododo, ti o si se ise rere, (Allahu) yoo pa awon asise re re fun un. O si maa mu un wo inu Ogba Idera, ti awon odo n san ni isale re. Olusegbere ni won ninu re titi laelae. Iyen si ni erenje nla
وَالَّذِينَ كَفَرُوا وَكَذَّبُوا بِآيَاتِنَا أُولَٰئِكَ أَصْحَابُ النَّارِ خَالِدِينَ فِيهَا ۖ وَبِئْسَ الْمَصِيرُ
Awon t’o si sai gbagbo, ti won tun pe awon ayah Wa niro, awon wonyen ni ero inu Ina. Olusegbere ni won ninu re. Ikangun naa si buru
Load More