Quran Apps in many lanuages:

Surah At-Tahrim Translated in Yoruba

يَا أَيُّهَا النَّبِيُّ لِمَ تُحَرِّمُ مَا أَحَلَّ اللَّهُ لَكَ ۖ تَبْتَغِي مَرْضَاتَ أَزْوَاجِكَ ۚ وَاللَّهُ غَفُورٌ رَحِيمٌ
Iwo Anabi, nitori ki ni o se maa so nnkan ti Allahu se ni eto fun o di eewo? Iwo n wa iyonu awon iyawo re. Allahu si ni Alaforijin, Asake-orun
قَدْ فَرَضَ اللَّهُ لَكُمْ تَحِلَّةَ أَيْمَانِكُمْ ۚ وَاللَّهُ مَوْلَاكُمْ ۖ وَهُوَ الْعَلِيمُ الْحَكِيمُ
Dajudaju Allahu ti se alaye ofin itanran ibura yin fun yin. Allahu ni Oluranlowo yin. Oun si ni Onimo, Ologbon
وَإِذْ أَسَرَّ النَّبِيُّ إِلَىٰ بَعْضِ أَزْوَاجِهِ حَدِيثًا فَلَمَّا نَبَّأَتْ بِهِ وَأَظْهَرَهُ اللَّهُ عَلَيْهِ عَرَّفَ بَعْضَهُ وَأَعْرَضَ عَنْ بَعْضٍ ۖ فَلَمَّا نَبَّأَهَا بِهِ قَالَتْ مَنْ أَنْبَأَكَ هَٰذَا ۖ قَالَ نَبَّأَنِيَ الْعَلِيمُ الْخَبِيرُ
Ranti nigba ti Anabi ba okan ninu awon iyawo re s’oro asiri. Nigba ti (eni t’o ba soro, iyen Hafsoh) si soro naa fun (‘A’isah), Allahu si fi han Anabi (pe elomiiran ti gbo si i). Anabi si so apa kan re (fun Hafsoh pe: "O ti fi oro Moriyah to ‘A’isah leti."). O si fi apa kan sile (iyen, oro nipa ipo arole). Amo nigba ti (Anabi) fi iro naa to o leti, Hafsoh) so pe: "Ta ni o fun o ni iro eyi?" (Anabi) so pe: "Onimo, Alamotan l’O fun mi ni iro naa
إِنْ تَتُوبَا إِلَى اللَّهِ فَقَدْ صَغَتْ قُلُوبُكُمَا ۖ وَإِنْ تَظَاهَرَا عَلَيْهِ فَإِنَّ اللَّهَ هُوَ مَوْلَاهُ وَجِبْرِيلُ وَصَالِحُ الْمُؤْمِنِينَ ۖ وَالْمَلَائِكَةُ بَعْدَ ذَٰلِكَ ظَهِيرٌ
Ti eyin mejeeji ba ronu piwada si odo Allahu, (O maa gba ironupiwada yin). Sebi okan yin kuku ti te (sibi ki Anabi ma fee Moriyah). Ti e ba si ran ara yin lowo (lati ko ibanuje) ba a, dajudaju Allahu ni Oluranlowo re, ati (molaika) Jibril ati eni rere ninu awon onigbagbo ododo. Leyin iyen, awon molaika ti won je oluranlowo (tun wa fun un)
عَسَىٰ رَبُّهُ إِنْ طَلَّقَكُنَّ أَنْ يُبْدِلَهُ أَزْوَاجًا خَيْرًا مِنْكُنَّ مُسْلِمَاتٍ مُؤْمِنَاتٍ قَانِتَاتٍ تَائِبَاتٍ عَابِدَاتٍ سَائِحَاتٍ ثَيِّبَاتٍ وَأَبْكَارًا
O see se, ti o ba ko yin sile, ki Oluwa re fi awon obinrin kan, ti won loore ju yin lo ropo fun un, (ti won maa je) musulumi, onigbagbo ododo, awon olutele-ase, awon oluronupiwada, olujosin, olugbaawe ni adelebo ati wundia
يَا أَيُّهَا الَّذِينَ آمَنُوا قُوا أَنْفُسَكُمْ وَأَهْلِيكُمْ نَارًا وَقُودُهَا النَّاسُ وَالْحِجَارَةُ عَلَيْهَا مَلَائِكَةٌ غِلَاظٌ شِدَادٌ لَا يَعْصُونَ اللَّهَ مَا أَمَرَهُمْ وَيَفْعَلُونَ مَا يُؤْمَرُونَ
Eyin ti e gbagbo ni ododo, e so emi ara yin ati awon ara ile yin nibi Ina. Eniyan ati okuta ni nnkan ikona re. Awon molaika t’o roro, ti won le ni eso re. Won ko nii yapa ase Allahu nibi ohun ti O ba pa lase fun won. Won si n se ohun ti won ba pa lase fun won
يَا أَيُّهَا الَّذِينَ كَفَرُوا لَا تَعْتَذِرُوا الْيَوْمَ ۖ إِنَّمَا تُجْزَوْنَ مَا كُنْتُمْ تَعْمَلُونَ
Eyin ti e sai gbagbo, e ma se saroye ni ojo oni. Ohun ti e n se nise ni A oo fi san yin ni esan
يَا أَيُّهَا الَّذِينَ آمَنُوا تُوبُوا إِلَى اللَّهِ تَوْبَةً نَصُوحًا عَسَىٰ رَبُّكُمْ أَنْ يُكَفِّرَ عَنْكُمْ سَيِّئَاتِكُمْ وَيُدْخِلَكُمْ جَنَّاتٍ تَجْرِي مِنْ تَحْتِهَا الْأَنْهَارُ يَوْمَ لَا يُخْزِي اللَّهُ النَّبِيَّ وَالَّذِينَ آمَنُوا مَعَهُ ۖ نُورُهُمْ يَسْعَىٰ بَيْنَ أَيْدِيهِمْ وَبِأَيْمَانِهِمْ يَقُولُونَ رَبَّنَا أَتْمِمْ لَنَا نُورَنَا وَاغْفِرْ لَنَا ۖ إِنَّكَ عَلَىٰ كُلِّ شَيْءٍ قَدِيرٌ
Eyin ti e gbagbo ni ododo, e ronu piwada si odo Allahu ni ironupiwada ododo. O see se pe Oluwa yin maa pa awon asise yin re fun yin. O si maa mu yin wo inu awon Ogba Idera ti awon odo n san ni isale re. Ni ojo ti Allahu ko nii doju ti Anabi ati awon t’o gbagbo ni ododo pelu re. Imole won yoo maa tan ni iwaju won ati ni owo otun won. Won yoo so pe: "Oluwa wa, pe imole wa fun wa, ki O si forijin wa. Dajudaju Iwo ni Alagbara lori gbogbo nnkan
يَا أَيُّهَا النَّبِيُّ جَاهِدِ الْكُفَّارَ وَالْمُنَافِقِينَ وَاغْلُظْ عَلَيْهِمْ ۚ وَمَأْوَاهُمْ جَهَنَّمُ ۖ وَبِئْسَ الْمَصِيرُ
Iwo Anabi, gbogun ti awon alaigbagbo ati awon sobe-selu musulumi. Ki o si le mo won. Ibugbe won si ni ina Jahanamo. Ikangun naa si buru
ضَرَبَ اللَّهُ مَثَلًا لِلَّذِينَ كَفَرُوا امْرَأَتَ نُوحٍ وَامْرَأَتَ لُوطٍ ۖ كَانَتَا تَحْتَ عَبْدَيْنِ مِنْ عِبَادِنَا صَالِحَيْنِ فَخَانَتَاهُمَا فَلَمْ يُغْنِيَا عَنْهُمَا مِنَ اللَّهِ شَيْئًا وَقِيلَ ادْخُلَا النَّارَ مَعَ الدَّاخِلِينَ
Allahu fi iyawo (Anabi) Nuh ati iyawo (Anabi) Lut se apeere fun awon t’o sai gbagbo. Awon mejeeji wa labe erusin meji rere ninu awon erusin Wa. Awon (obinrin) mejeeji si janba awon oko won. Awon oko won ko si fi kini kan ro won loro lodo Allahu. A o si so fun awon obinrin mejeeji pe: "E wo inu Ina pelu awon oluwole (sinu Ina)
Load More