Quran Apps in many lanuages:

Surah At-Talaq Translated in Yoruba

يَا أَيُّهَا النَّبِيُّ إِذَا طَلَّقْتُمُ النِّسَاءَ فَطَلِّقُوهُنَّ لِعِدَّتِهِنَّ وَأَحْصُوا الْعِدَّةَ ۖ وَاتَّقُوا اللَّهَ رَبَّكُمْ ۖ لَا تُخْرِجُوهُنَّ مِنْ بُيُوتِهِنَّ وَلَا يَخْرُجْنَ إِلَّا أَنْ يَأْتِينَ بِفَاحِشَةٍ مُبَيِّنَةٍ ۚ وَتِلْكَ حُدُودُ اللَّهِ ۚ وَمَنْ يَتَعَدَّ حُدُودَ اللَّهِ فَقَدْ ظَلَمَ نَفْسَهُ ۚ لَا تَدْرِي لَعَلَّ اللَّهَ يُحْدِثُ بَعْدَ ذَٰلِكَ أَمْرًا
Iwo Anabi, nigba ti e ba fe ko awon obinrin sile, e ko won sile pelu sise onka ojo opo fun ikosile won. Ki e si so onka ojo opo. Ki e beru Allahu, Oluwa yin. E ma se mu won jade kuro ninu ile won, awon naa ko si gbodo jade afi ti won ba lo se ibaje t’o foju han. Iwonyen si ni awon enu-ala ti Allahu gbekale. Enikeni ti o ba tayo awon enu-ala ti Allahu gbekale, o kuku ti sabosi si emi ara re. Iwo ko si mo boya Allahu maa mu oro titun sele leyin iyen
فَإِذَا بَلَغْنَ أَجَلَهُنَّ فَأَمْسِكُوهُنَّ بِمَعْرُوفٍ أَوْ فَارِقُوهُنَّ بِمَعْرُوفٍ وَأَشْهِدُوا ذَوَيْ عَدْلٍ مِنْكُمْ وَأَقِيمُوا الشَّهَادَةَ لِلَّهِ ۚ ذَٰلِكُمْ يُوعَظُ بِهِ مَنْ كَانَ يُؤْمِنُ بِاللَّهِ وَالْيَوْمِ الْآخِرِ ۚ وَمَنْ يَتَّقِ اللَّهَ يَجْعَلْ لَهُ مَخْرَجًا
Nigba ti won ba fe pari onka ojo opo won, e mu won modo ni ona t’o dara tabi ki e ko won sile ni ona t’o dara. E fi awon onideede meji ninu yin jerii si i. Ki e si gbe ijerii naa duro ni titori ti Allahu. Iyen ni A n fi se waasi fun enikeni ti o ba ni igbagbo ododo ninu Allahu ati Ojo Ikeyin. Enikeni ti o ba n beru Allahu, O maa fun un ni ona abayo (ninu isoro)
وَيَرْزُقْهُ مِنْ حَيْثُ لَا يَحْتَسِبُ ۚ وَمَنْ يَتَوَكَّلْ عَلَى اللَّهِ فَهُوَ حَسْبُهُ ۚ إِنَّ اللَّهَ بَالِغُ أَمْرِهِ ۚ قَدْ جَعَلَ اللَّهُ لِكُلِّ شَيْءٍ قَدْرًا
O si maa pese fun un ni aye ti ko ti rokan. Ati pe enikeni ti o ba gbekele Allahu, O maa to o. Dajudaju Allahu yoo mu oro Re de opin. Dajudaju Allahu ti ko odiwon akoko fun gbogbo nnkan
وَاللَّائِي يَئِسْنَ مِنَ الْمَحِيضِ مِنْ نِسَائِكُمْ إِنِ ارْتَبْتُمْ فَعِدَّتُهُنَّ ثَلَاثَةُ أَشْهُرٍ وَاللَّائِي لَمْ يَحِضْنَ ۚ وَأُولَاتُ الْأَحْمَالِ أَجَلُهُنَّ أَنْ يَضَعْنَ حَمْلَهُنَّ ۚ وَمَنْ يَتَّقِ اللَّهَ يَجْعَلْ لَهُ مِنْ أَمْرِهِ يُسْرًا
Awon obinrin t’o ti soreti nu nipa nnkan osu sise ninu awon obinrin yin, ti e ba seyemeji, onka ojo ikosile won ni osu meta. (Bee naa ni fun) awon ti ko ti i maa se nnkan osu. Awon oloyun, ipari onka ojo opo ikosile tiwon ni pe ki won bi oyun inu won. Enikeni ti o ba n beru Allahu, O maa se oro re ni irorun
ذَٰلِكَ أَمْرُ اللَّهِ أَنْزَلَهُ إِلَيْكُمْ ۚ وَمَنْ يَتَّقِ اللَّهَ يُكَفِّرْ عَنْهُ سَيِّئَاتِهِ وَيُعْظِمْ لَهُ أَجْرًا
Iyen ni ase Allahu, ti O sokale fun yin. Enikeni ti o ba n beru Allahu, O maa pa awon asise re re. O si maa je ki esan re tobi
أَسْكِنُوهُنَّ مِنْ حَيْثُ سَكَنْتُمْ مِنْ وُجْدِكُمْ وَلَا تُضَارُّوهُنَّ لِتُضَيِّقُوا عَلَيْهِنَّ ۚ وَإِنْ كُنَّ أُولَاتِ حَمْلٍ فَأَنْفِقُوا عَلَيْهِنَّ حَتَّىٰ يَضَعْنَ حَمْلَهُنَّ ۚ فَإِنْ أَرْضَعْنَ لَكُمْ فَآتُوهُنَّ أُجُورَهُنَّ ۖ وَأْتَمِرُوا بَيْنَكُمْ بِمَعْرُوفٍ ۖ وَإِنْ تَعَاسَرْتُمْ فَسَتُرْضِعُ لَهُ أُخْرَىٰ
E fun won ni ibugbe ninu ibugbe yin bi aye se gba yin mo. E ma se ni won lara lati ko ifunpinpin ba won. Ti won ba je oloyun, e nawo le won lori titi won yoo fi bi oyun inu won. Ti won ba n fun omo yin ni oyan mu, e fun won ni owo-oya won. E damoran laaarin ara yin ni ona t’o dara. Ti oro ko ba si rogbo laaarin ara yin, ki elomiiran ba oko (fun omo) ni oyan mu
لِيُنْفِقْ ذُو سَعَةٍ مِنْ سَعَتِهِ ۖ وَمَنْ قُدِرَ عَلَيْهِ رِزْقُهُ فَلْيُنْفِقْ مِمَّا آتَاهُ اللَّهُ ۚ لَا يُكَلِّفُ اللَّهُ نَفْسًا إِلَّا مَا آتَاهَا ۚ سَيَجْعَلُ اللَّهُ بَعْدَ عُسْرٍ يُسْرًا
Ki oloro na ninu oro re. Eni ti A si diwon arisiki re fun (niwonba), ki o na ninu ohun ti Allahu fun un. Allahu ko labo emi kan lorun ayafi nnkan ti O fun un. Allahu yo si mu irorun wa leyin inira
وَكَأَيِّنْ مِنْ قَرْيَةٍ عَتَتْ عَنْ أَمْرِ رَبِّهَا وَرُسُلِهِ فَحَاسَبْنَاهَا حِسَابًا شَدِيدًا وَعَذَّبْنَاهَا عَذَابًا نُكْرًا
Meloo meloo ninu awon ilu ti won yapa ase Oluwa Re ati awon Ojise Re. A si maa siro ise won ni isiro lile. Ati pe A maa je won niya t’o buru gan-an
فَذَاقَتْ وَبَالَ أَمْرِهَا وَكَانَ عَاقِبَةُ أَمْرِهَا خُسْرًا
Nitori naa, won to iya oran won wo. Ikangun oro won si je ofo
أَعَدَّ اللَّهُ لَهُمْ عَذَابًا شَدِيدًا ۖ فَاتَّقُوا اللَّهَ يَا أُولِي الْأَلْبَابِ الَّذِينَ آمَنُوا ۚ قَدْ أَنْزَلَ اللَّهُ إِلَيْكُمْ ذِكْرًا
Allahu ti pese iya lile sile de won. Nitori naa, e beru Allahu, eyin onilaakaye ti e gbagbo ni ododo. Allahu kuku ti so iranti kale fun yin
Load More