Quran Apps in many lanuages:

Surah At-Tawba Translated in Yoruba

بَرَاءَةٌ مِنَ اللَّهِ وَرَسُولِهِ إِلَى الَّذِينَ عَاهَدْتُمْ مِنَ الْمُشْرِكِينَ
(Eyi ni) iyowo-yose lati odo Allahu ati Ojise Re si awon ti e se adehun fun ninu awon osebo
فَسِيحُوا فِي الْأَرْضِ أَرْبَعَةَ أَشْهُرٍ وَاعْلَمُوا أَنَّكُمْ غَيْرُ مُعْجِزِي اللَّهِ ۙ وَأَنَّ اللَّهَ مُخْزِي الْكَافِرِينَ
Nitori naa, (eyin osebo) e rin (kiri) lori ile fun osu merin. Ki e si mo pe dajudaju eyin ko le moribo (ninu iya) Allahu. Ati pe dajudaju Allahu yoo doju ti awon alaigbagbo
وَأَذَانٌ مِنَ اللَّهِ وَرَسُولِهِ إِلَى النَّاسِ يَوْمَ الْحَجِّ الْأَكْبَرِ أَنَّ اللَّهَ بَرِيءٌ مِنَ الْمُشْرِكِينَ ۙ وَرَسُولُهُ ۚ فَإِنْ تُبْتُمْ فَهُوَ خَيْرٌ لَكُمْ ۖ وَإِنْ تَوَلَّيْتُمْ فَاعْلَمُوا أَنَّكُمْ غَيْرُ مُعْجِزِي اللَّهِ ۗ وَبَشِّرِ الَّذِينَ كَفَرُوا بِعَذَابٍ أَلِيمٍ
Ikede kan lati odo Allahu ati Ojise Re si awon eniyan ni ojo Hajj Nla ni pe, “Dajudaju Allahu yowoyose (ninu oro) awon osebo. Ojise Re naa (yowoyose). Ti e ba ronu piwada, o si loore julo fun yin. Ti e ba gbunri, e mo pe dajudaju e o le moribo ninu (iya) Allahu.” Ki o si fun awon t’o sai gbagbo ni iro iya eleta-elero
إِلَّا الَّذِينَ عَاهَدْتُمْ مِنَ الْمُشْرِكِينَ ثُمَّ لَمْ يَنْقُصُوكُمْ شَيْئًا وَلَمْ يُظَاهِرُوا عَلَيْكُمْ أَحَدًا فَأَتِمُّوا إِلَيْهِمْ عَهْدَهُمْ إِلَىٰ مُدَّتِهِمْ ۚ إِنَّ اللَّهَ يُحِبُّ الْمُتَّقِينَ
Ayafi awon ti e ba se adehun ninu awon osebo, leyin naa, ti won ko si fi ona kan kan ye adehun yin, ti won ko si satileyin fun eni kan kan le yin lori. Nitori naa, e pe adehun won fun won titi di asiko won. Dajudaju Allahu nifee awon oluberu (Re)
فَإِذَا انْسَلَخَ الْأَشْهُرُ الْحُرُمُ فَاقْتُلُوا الْمُشْرِكِينَ حَيْثُ وَجَدْتُمُوهُمْ وَخُذُوهُمْ وَاحْصُرُوهُمْ وَاقْعُدُوا لَهُمْ كُلَّ مَرْصَدٍ ۚ فَإِنْ تَابُوا وَأَقَامُوا الصَّلَاةَ وَآتَوُا الزَّكَاةَ فَخَلُّوا سَبِيلَهُمْ ۚ إِنَّ اللَّهَ غَفُورٌ رَحِيمٌ
Nitori naa, nigba ti awon osu owo ba lo tan , e pa awon osebo nibikibi ti e ba ti ba won. E mu won, e sede mo won, ki e si ba de won ni gbogbo ibuba. Ti won ba si ronu piwada, ti won n kirun, ti won si n yo Zakah, e yago fun won loju ona. Dajudaju Allahu ni Alaforijin, Asake-orun
وَإِنْ أَحَدٌ مِنَ الْمُشْرِكِينَ اسْتَجَارَكَ فَأَجِرْهُ حَتَّىٰ يَسْمَعَ كَلَامَ اللَّهِ ثُمَّ أَبْلِغْهُ مَأْمَنَهُ ۚ ذَٰلِكَ بِأَنَّهُمْ قَوْمٌ لَا يَعْلَمُونَ
Ti eni kan ninu awon osebo ba wa eto aabo wa sodo re, s’eto aabo fun un titi o fi maa gbo oro Allahu. Leyin naa, mu u de aye ifokanbale re. Iyen nitori pe dajudaju awon ni ijo ti ko nimo
كَيْفَ يَكُونُ لِلْمُشْرِكِينَ عَهْدٌ عِنْدَ اللَّهِ وَعِنْدَ رَسُولِهِ إِلَّا الَّذِينَ عَاهَدْتُمْ عِنْدَ الْمَسْجِدِ الْحَرَامِ ۖ فَمَا اسْتَقَامُوا لَكُمْ فَاسْتَقِيمُوا لَهُمْ ۚ إِنَّ اللَّهَ يُحِبُّ الْمُتَّقِينَ
Bawo ni adehun kan yoo se wa fun awon osebo lodo Allahu ati lodo Ojise Re yato si awon ti e ba se adehun nitosi Mosalasi Haram? Nitori naa, ti won ba duro deede pelu yin, e duro deede pelu won. Dajudaju Allahu nifee awon oluberu (Re)
كَيْفَ وَإِنْ يَظْهَرُوا عَلَيْكُمْ لَا يَرْقُبُوا فِيكُمْ إِلًّا وَلَا ذِمَّةً ۚ يُرْضُونَكُمْ بِأَفْوَاهِهِمْ وَتَأْبَىٰ قُلُوبُهُمْ وَأَكْثَرُهُمْ فَاسِقُونَ
Bawo (ni adehun kan yoo se wa fun won) nigba ti o je pe ti won ba bori yin, won ko nii so okun ibi ati adehun. Won n fi enu won wi pe awon yonu si yin, okan won si ko o. Opolopo won si ni obileje
اشْتَرَوْا بِآيَاتِ اللَّهِ ثَمَنًا قَلِيلًا فَصَدُّوا عَنْ سَبِيلِهِ ۚ إِنَّهُمْ سَاءَ مَا كَانُوا يَعْمَلُونَ
Won ta awon ayah Allahu ni owo pooku, won si seri awon eniyan kuro loju ona (esin) Re. Dajudaju awon (wonyi), ohun ti won n se nise buru
لَا يَرْقُبُونَ فِي مُؤْمِنٍ إِلًّا وَلَا ذِمَّةً ۚ وَأُولَٰئِكَ هُمُ الْمُعْتَدُونَ
Awon osebo ko nii so okun ibi ati adehun kan fun onigbagbo ododo kan. Awon wonyen, awon si ni olutayo enu-ala
Load More