Surah Fussilat Translated in Yoruba
كِتَابٌ فُصِّلَتْ آيَاتُهُ قُرْآنًا عَرَبِيًّا لِقَوْمٍ يَعْلَمُونَ
(Eyi ni) Tira kan ti Won salaye awon ayah inu re; al-Ƙur’an ni ede Larubawa ni fun ijo t’o nimo
بَشِيرًا وَنَذِيرًا فَأَعْرَضَ أَكْثَرُهُمْ فَهُمْ لَا يَسْمَعُونَ
(O je) iro-idunnu ati ikilo, sugbon opolopo won gbunri kuro nibe. Won ko si teti si i
وَقَالُوا قُلُوبُنَا فِي أَكِنَّةٍ مِمَّا تَدْعُونَا إِلَيْهِ وَفِي آذَانِنَا وَقْرٌ وَمِنْ بَيْنِنَا وَبَيْنِكَ حِجَابٌ فَاعْمَلْ إِنَّنَا عَامِلُونَ
Won si wi pe: "Okan wa wa ni titi pa si ohun ti e n pe wa si. Edidi si wa ninu eti wa. Ati pe gaga wa laaarin awa ati iwo. Nitori naa, maa se tire. Dajudaju awa naa n se tiwa
قُلْ إِنَّمَا أَنَا بَشَرٌ مِثْلُكُمْ يُوحَىٰ إِلَيَّ أَنَّمَا إِلَٰهُكُمْ إِلَٰهٌ وَاحِدٌ فَاسْتَقِيمُوا إِلَيْهِ وَاسْتَغْفِرُوهُ ۗ وَوَيْلٌ لِلْمُشْرِكِينَ
So pe: "Abara bi iru yin kuku ni emi naa. Won n fi imisi ranse si mi ni, pe Olohun yin, Olohun Okan soso ni. Nitori naa, e duro sinsin ti I, ki e si toro aforijin ni odo Re. Egbe si ni fun awon osebo
الَّذِينَ لَا يُؤْتُونَ الزَّكَاةَ وَهُمْ بِالْآخِرَةِ هُمْ كَافِرُونَ
awon ti ko yo Zakah. Awon si ni alaigbagbo ninu Ojo Ikeyin
إِنَّ الَّذِينَ آمَنُوا وَعَمِلُوا الصَّالِحَاتِ لَهُمْ أَجْرٌ غَيْرُ مَمْنُونٍ
Dajudaju awon t’o gbagbo ni ododo, ti won si se awon ise rere, esan ti ko nii pedin n be fun won
قُلْ أَئِنَّكُمْ لَتَكْفُرُونَ بِالَّذِي خَلَقَ الْأَرْضَ فِي يَوْمَيْنِ وَتَجْعَلُونَ لَهُ أَنْدَادًا ۚ ذَٰلِكَ رَبُّ الْعَالَمِينَ
So pe: "Se dajudaju eyin maa sai gbagbo ninu Eni ti O seda ile fun ojo meji, e si n so (eda Re) di akegbe fun Un?" Iyen si ni Oluwa gbogbo eda
وَجَعَلَ فِيهَا رَوَاسِيَ مِنْ فَوْقِهَا وَبَارَكَ فِيهَا وَقَدَّرَ فِيهَا أَقْوَاتَهَا فِي أَرْبَعَةِ أَيَّامٍ سَوَاءً لِلسَّائِلِينَ
O si fi awon apata sinu ile lati oke re. O fi ibukun sinu re. O si pebubu awon arisiki (ati ohun amusoro) sinu re laaarin ojo merin. (Awon ojo naa) dogba (sira won) fun awon olubeere (nipa re). o jeyo ninu won pe “Allahu seda awon sanmo ati ile fun ojo mefa.” O wa bee ninu surah al-’A‘rof; 7:54 nnkan naa ko nii dohun afi pelu gbolohun “kunfayakun”. Awon eda ti ko ba si jemo eroja iseda tabi awon eda ti Allahu (subhanahu wa ta’ala) ko so nipa eroja iseda won fun wa Allahu l’O kuku nimo nipa iseda awon eda Re awon eda kan di eda pelu gbolohun “kunfayakun” nikan. Awon eda kan si di eda nipase eroja iseda ati gbolohun “kunfayakun”. Allahu n seda ohun ti O ba fe ni ona ti O ba fe. Nitori naa gbolohun “kunfayakun” t’o je ti Allahu nikan soso ko le so Allahu di olukanju. Ikanju ki i se iroyin rere fun Allahu. Bi Allahu se gbaroyin pelu gbolohun “kunfayakun”
Load More