Quran Apps in many lanuages:

Surah Hud Translated in Yoruba

الر ۚ كِتَابٌ أُحْكِمَتْ آيَاتُهُ ثُمَّ فُصِّلَتْ مِنْ لَدُنْ حَكِيمٍ خَبِيرٍ
’Alif lam ro. (Eyi ni) Tira ti won ti to awon ayah inu re ni atogun rege, leyin naa won salaye re yekeyeke lati odo Ologbon, Alamotan
أَلَّا تَعْبُدُوا إِلَّا اللَّهَ ۚ إِنَّنِي لَكُمْ مِنْهُ نَذِيرٌ وَبَشِيرٌ
(A ti salaye re) pe e ma josin fun kini kan afi Allahu. Dajudaju emi ni olukilo ati oniroo idunnu fun yin lati odo Re
وَأَنِ اسْتَغْفِرُوا رَبَّكُمْ ثُمَّ تُوبُوا إِلَيْهِ يُمَتِّعْكُمْ مَتَاعًا حَسَنًا إِلَىٰ أَجَلٍ مُسَمًّى وَيُؤْتِ كُلَّ ذِي فَضْلٍ فَضْلَهُ ۖ وَإِنْ تَوَلَّوْا فَإِنِّي أَخَافُ عَلَيْكُمْ عَذَابَ يَوْمٍ كَبِيرٍ
(A ti salaye re) pe ki e toro aforijin lodo Oluwa yin. Leyin naa, ki e ronu piwada sodo Re. O maa fun yin ni igbadun daadaa titi di gbedeke akoko kan. O maa fun onise-asegbore ni esan ise asegbore re. Ti e ba si peyin da, dajudaju emi n paya iya Ojo nla fun yin
إِلَى اللَّهِ مَرْجِعُكُمْ ۖ وَهُوَ عَلَىٰ كُلِّ شَيْءٍ قَدِيرٌ
Odo Allahu ni ibupadasi yin. Oun si ni Alagbara lori gbogbo nnkan
أَلَا إِنَّهُمْ يَثْنُونَ صُدُورَهُمْ لِيَسْتَخْفُوا مِنْهُ ۚ أَلَا حِينَ يَسْتَغْشُونَ ثِيَابَهُمْ يَعْلَمُ مَا يُسِرُّونَ وَمَا يُعْلِنُونَ ۚ إِنَّهُ عَلِيمٌ بِذَاتِ الصُّدُورِ
Gbo, dajudaju awon sobe-selu musulumi n bo ohun ti n be ninu igba-aya won lati le fara pamo fun Allahu. Kiye si i, nigba ti won n yiso won bora, Allahu mo nnkan ti won n fi pamo ati nnkan ti won n safi han re. Dajudaju Oun ni Onimo nipa nnkan ti n be ninu igba-aya eda
وَمَا مِنْ دَابَّةٍ فِي الْأَرْضِ إِلَّا عَلَى اللَّهِ رِزْقُهَا وَيَعْلَمُ مُسْتَقَرَّهَا وَمُسْتَوْدَعَهَا ۚ كُلٌّ فِي كِتَابٍ مُبِينٍ
Ko si eda abemi kan t’o wa lori ile afi ki arisiki re wa lodo Allahu. O si mo ibugbe re (nile aye) ati ile ti o maa ku si. Gbogbo re ti wa ninu akosile t’o yanju
وَهُوَ الَّذِي خَلَقَ السَّمَاوَاتِ وَالْأَرْضَ فِي سِتَّةِ أَيَّامٍ وَكَانَ عَرْشُهُ عَلَى الْمَاءِ لِيَبْلُوَكُمْ أَيُّكُمْ أَحْسَنُ عَمَلًا ۗ وَلَئِنْ قُلْتَ إِنَّكُمْ مَبْعُوثُونَ مِنْ بَعْدِ الْمَوْتِ لَيَقُولَنَّ الَّذِينَ كَفَرُوا إِنْ هَٰذَا إِلَّا سِحْرٌ مُبِينٌ
Oun ni Eni ti O seda awon sanmo ati ile fun ojo mefa - Ite ola Re si wa lori omi (siwaju eyi) – nitori ki O le dan yin wo pe, ewo ninu yin l’o dara julo (nibi) ise rere. Ti o ba kuku so pe dajudaju won yoo gbe yin dide leyin iku, dajudaju awon t’o sai gbagbo yoo wi pe: “Eyi ko je kini kan bi ko se idan ponnbele.”
وَلَئِنْ أَخَّرْنَا عَنْهُمُ الْعَذَابَ إِلَىٰ أُمَّةٍ مَعْدُودَةٍ لَيَقُولُنَّ مَا يَحْبِسُهُ ۗ أَلَا يَوْمَ يَأْتِيهِمْ لَيْسَ مَصْرُوفًا عَنْهُمْ وَحَاقَ بِهِمْ مَا كَانُوا بِهِ يَسْتَهْزِئُونَ
Dajudaju ti A ba sun iya siwaju fun won di igba t’o ni onka, dajudaju won yoo wi pe: “Ki l’o n da a duro na?” Gbo, ni ojo ti iya yoo de ba won, ko nii se e gbe kuro fun won. Ati pe ohun ti won n fi se yeye si maa diya t’o maa yi won po
وَلَئِنْ أَذَقْنَا الْإِنْسَانَ مِنَّا رَحْمَةً ثُمَّ نَزَعْنَاهَا مِنْهُ إِنَّهُ لَيَئُوسٌ كَفُورٌ
Ati pe dajudaju ti A ba fi ike kan to eniyan lenu wo lati odo Wa, leyin naa, ti A ba gba a kuro lowo re, dajudaju o maa di olusoretinu, alaimoore
وَلَئِنْ أَذَقْنَاهُ نَعْمَاءَ بَعْدَ ضَرَّاءَ مَسَّتْهُ لَيَقُولَنَّ ذَهَبَ السَّيِّئَاتُ عَنِّي ۚ إِنَّهُ لَفَرِحٌ فَخُورٌ
Dajudaju ti A ba si fun un ni idera towo leyin inira t’o fowo ba a, dajudaju o maa wi pe: “Awon aburu ti kuro lodo mi.” Dajudaju o maa di alayoporo, onifaari
Load More