Quran Apps in many lanuages:

Surah Muhammad Translated in Yoruba

الَّذِينَ كَفَرُوا وَصَدُّوا عَنْ سَبِيلِ اللَّهِ أَضَلَّ أَعْمَالَهُمْ
Awon t’o sai gbagbo, ti won tun seri awon eniyan kuro loju ona (esin) Allahu, (Allahu) maa so ise won dofo
وَالَّذِينَ آمَنُوا وَعَمِلُوا الصَّالِحَاتِ وَآمَنُوا بِمَا نُزِّلَ عَلَىٰ مُحَمَّدٍ وَهُوَ الْحَقُّ مِنْ رَبِّهِمْ ۙ كَفَّرَ عَنْهُمْ سَيِّئَاتِهِمْ وَأَصْلَحَ بَالَهُمْ
Awon t’o gbagbo ni ododo, ti won se awon ise rere, ti won tun gbagbo ninu ohun ti Won sokale fun (Anabi) Muhammad, ohun si ni ododo lati odo Oluwa won, (Allahu) maa pa awon (ise) aburu won re, O si maa se atunse oro won si daadaa
ذَٰلِكَ بِأَنَّ الَّذِينَ كَفَرُوا اتَّبَعُوا الْبَاطِلَ وَأَنَّ الَّذِينَ آمَنُوا اتَّبَعُوا الْحَقَّ مِنْ رَبِّهِمْ ۚ كَذَٰلِكَ يَضْرِبُ اللَّهُ لِلنَّاسِ أَمْثَالَهُمْ
Iyen nitori pe dajudaju awon t’o sai gbagbo tele iro. Ati pe dajudaju awon t’o gbagbo tele ododo lati odo Oluwa won. Bayen ni Allahu se n fi apejuwe won lele fun awon eniyan
فَإِذَا لَقِيتُمُ الَّذِينَ كَفَرُوا فَضَرْبَ الرِّقَابِ حَتَّىٰ إِذَا أَثْخَنْتُمُوهُمْ فَشُدُّوا الْوَثَاقَ فَإِمَّا مَنًّا بَعْدُ وَإِمَّا فِدَاءً حَتَّىٰ تَضَعَ الْحَرْبُ أَوْزَارَهَا ۚ ذَٰلِكَ وَلَوْ يَشَاءُ اللَّهُ لَانْتَصَرَ مِنْهُمْ وَلَٰكِنْ لِيَبْلُوَ بَعْضَكُمْ بِبَعْضٍ ۗ وَالَّذِينَ قُتِلُوا فِي سَبِيلِ اللَّهِ فَلَنْ يُضِلَّ أَعْمَالَهُمْ
Nitori naa, nigba ti e ba pade awon t’o sai gbagbo (loju ogun esin), e maa be won lorun nso titi di igba ti e maa fi bori won. (Ti e ba segun) ki e de won nigbekun. Leyin naa, e le tu won sile ni ofe tabi ki e tu won sile pelu owo itusile titi (okunfa) ogun esin yoo fi kase nile. Iyen (wa bee). Ti o ba je pe Allahu ba fe, iba gbesan funra Re (lai nii la ogun jija lo), sugbon nitori ki O le dan apa kan yin wo lara apa kan ni. Awon musulumi ti won si pa si oju ogun esin, Allahu ko nii so ise won dofo
سَيَهْدِيهِمْ وَيُصْلِحُ بَالَهُمْ
O maa to won sona. O si maa tun oro won se si daadaa
وَيُدْخِلُهُمُ الْجَنَّةَ عَرَّفَهَا لَهُمْ
O maa fi won wo inu Ogba Idera, eyi ti O ti fi mo won
يَا أَيُّهَا الَّذِينَ آمَنُوا إِنْ تَنْصُرُوا اللَّهَ يَنْصُرْكُمْ وَيُثَبِّتْ أَقْدَامَكُمْ
Eyin ti e gbagbo ni ododo, ti e ba ran (esin) Allahu lowo, (Allahu) maa ran yin lowo. O si maa mu ese yin duro sinsin
وَالَّذِينَ كَفَرُوا فَتَعْسًا لَهُمْ وَأَضَلَّ أَعْمَالَهُمْ
Awon t’o sai gbagbo, egbe ni fun won. (Allahu) si maa ba ise won je
ذَٰلِكَ بِأَنَّهُمْ كَرِهُوا مَا أَنْزَلَ اللَّهُ فَأَحْبَطَ أَعْمَالَهُمْ
Iyen nitori pe dajudaju won korira ohun ti Allahu sokale. Nitori naa, (Allahu) si ba ise won je
أَفَلَمْ يَسِيرُوا فِي الْأَرْضِ فَيَنْظُرُوا كَيْفَ كَانَ عَاقِبَةُ الَّذِينَ مِنْ قَبْلِهِمْ ۚ دَمَّرَ اللَّهُ عَلَيْهِمْ ۖ وَلِلْكَافِرِينَ أَمْثَالُهَا
Se won ko rin kiri lori ile ki won wo bi ikangun awon t’o siwaju won se ri? Allahu pa won re. Iru re tun wa fun awon alaigbagbo
Load More