Surah Saba Translated in Yoruba
الْحَمْدُ لِلَّهِ الَّذِي لَهُ مَا فِي السَّمَاوَاتِ وَمَا فِي الْأَرْضِ وَلَهُ الْحَمْدُ فِي الْآخِرَةِ ۚ وَهُوَ الْحَكِيمُ الْخَبِيرُ
Gbogbo ope n je ti Allahu, Eni ti ohunkohun t’o wa ninu awon sanmo ati ohunkohun t’o wa ninu ile n je tiRe. Ati pe tiRe ni gbogbo ope ni orun. Oun si ni Ologbon, Alamotan
يَعْلَمُ مَا يَلِجُ فِي الْأَرْضِ وَمَا يَخْرُجُ مِنْهَا وَمَا يَنْزِلُ مِنَ السَّمَاءِ وَمَا يَعْرُجُ فِيهَا ۚ وَهُوَ الرَّحِيمُ الْغَفُورُ
O mo ohunkohun t’o n wonu ile ati ohunkohun t’o n jade latinu re. (O mo) ohunkohun t’o n sokale latinu sanmo ati ohunkohun t’o n gunke lo sinu re. Oun si ni Asake-orun, Alaforijin
وَقَالَ الَّذِينَ كَفَرُوا لَا تَأْتِينَا السَّاعَةُ ۖ قُلْ بَلَىٰ وَرَبِّي لَتَأْتِيَنَّكُمْ عَالِمِ الْغَيْبِ ۖ لَا يَعْزُبُ عَنْهُ مِثْقَالُ ذَرَّةٍ فِي السَّمَاوَاتِ وَلَا فِي الْأَرْضِ وَلَا أَصْغَرُ مِنْ ذَٰلِكَ وَلَا أَكْبَرُ إِلَّا فِي كِتَابٍ مُبِينٍ
Awon alaigbagbo wi pe: “Akoko naa ko nii de ba wa.” So pe: “Bee ko. Emi fi Oluwa mi bura. Dajudaju o maa de ba yin (lati odo) Onimo-ikoko (Eni ti) odiwon omo ina-igun ko pamo fun ninu sanmo ati ninu ile. (Ko si nnkan ti o) kere si iyen tabi ti o tobi (ju u lo) afi ki o wa ninu akosile t’o yanju.”
لِيَجْزِيَ الَّذِينَ آمَنُوا وَعَمِلُوا الصَّالِحَاتِ ۚ أُولَٰئِكَ لَهُمْ مَغْفِرَةٌ وَرِزْقٌ كَرِيمٌ
(O maa sele) nitori ki Allahu le san esan fun awon t’o gbagbo ni ododo, ti won tun se ise rere. Awon wonyen ni aforijin ati ese alapon-onle n be fun
وَالَّذِينَ سَعَوْا فِي آيَاتِنَا مُعَاجِزِينَ أُولَٰئِكَ لَهُمْ عَذَابٌ مِنْ رِجْزٍ أَلِيمٌ
Ati pe awon t’o se ise buruku nipa awon ayah Wa, (ti won lero pe) awon mori bo ninu iya; awon wonyen ni iya eleta-elero t’o buru n be fun
وَيَرَى الَّذِينَ أُوتُوا الْعِلْمَ الَّذِي أُنْزِلَ إِلَيْكَ مِنْ رَبِّكَ هُوَ الْحَقَّ وَيَهْدِي إِلَىٰ صِرَاطِ الْعَزِيزِ الْحَمِيدِ
Awon ti A fun ni imo ri i pe eyi ti won sokale fun o lati odo Oluwa re, ohun ni ododo, ati pe o n se itosona si ona Alagbara, Eleyin
وَقَالَ الَّذِينَ كَفَرُوا هَلْ نَدُلُّكُمْ عَلَىٰ رَجُلٍ يُنَبِّئُكُمْ إِذَا مُزِّقْتُمْ كُلَّ مُمَزَّقٍ إِنَّكُمْ لَفِي خَلْقٍ جَدِيدٍ
Awon t’o sai gbagbo wi pe: “Se ki a toka yin si okunrin kan ti o maa fun yin ni iro pe nigba ti won ba fon yin ka tan patapata (sinu erupe), pe dajudaju e maa pada wa ni eda titun
أَفْتَرَىٰ عَلَى اللَّهِ كَذِبًا أَمْ بِهِ جِنَّةٌ ۗ بَلِ الَّذِينَ لَا يُؤْمِنُونَ بِالْآخِرَةِ فِي الْعَذَابِ وَالضَّلَالِ الْبَعِيدِ
Se o da adapa iro mo Allahu ni tabi alujannu n be lara re ni?” Rara o! Awon ti ko gba Ojo Ikeyin gbo ti wa ninu iya ati isina t’o jinna
أَفَلَمْ يَرَوْا إِلَىٰ مَا بَيْنَ أَيْدِيهِمْ وَمَا خَلْفَهُمْ مِنَ السَّمَاءِ وَالْأَرْضِ ۚ إِنْ نَشَأْ نَخْسِفْ بِهِمُ الْأَرْضَ أَوْ نُسْقِطْ عَلَيْهِمْ كِسَفًا مِنَ السَّمَاءِ ۚ إِنَّ فِي ذَٰلِكَ لَآيَةً لِكُلِّ عَبْدٍ مُنِيبٍ
Se won ko ri ohun t’o n be niwaju won ati ohun t’o n be leyin won ni sanmo ati ile? Ti A ba fe, Awa iba je ki ile ri mo won lese, tabi ki A ja apa kan sanmo lule le won lori mole. Dajudaju ami kan wa ninu iyen fun gbogbo erusin, oluronupiwada
وَلَقَدْ آتَيْنَا دَاوُودَ مِنَّا فَضْلًا ۖ يَا جِبَالُ أَوِّبِي مَعَهُ وَالطَّيْرَ ۖ وَأَلَنَّا لَهُ الْحَدِيدَ
Dajudaju A ti fun (Anabi) Dawud ni oore ajulo lati odo Wa; Eyin apata, e se afomo pelu re. (A pe) awon eye naa (pe ki won se bee.) A si ro irin fun un
Load More