Surah Sad Translated in Yoruba

بَلِ الَّذِينَ كَفَرُوا فِي عِزَّةٍ وَشِقَاقٍ

Sibesibe awon t’o sai gbagbo wa ninu igberaga ati iyapa (ododo)
كَمْ أَهْلَكْنَا مِنْ قَبْلِهِمْ مِنْ قَرْنٍ فَنَادَوْا وَلَاتَ حِينَ مَنَاصٍ

Meloo meloo ninu awon iran ti A ti pare siwaju won. Nigba naa, won kigbe too nigba ti ko si ibusasi kan
وَعَجِبُوا أَنْ جَاءَهُمْ مُنْذِرٌ مِنْهُمْ ۖ وَقَالَ الْكَافِرُونَ هَٰذَا سَاحِرٌ كَذَّابٌ

Won seemo pe olukilo kan ninu won wa ba won. Awon alaigbagbo si wi pe: "Eyi ni opidan, opuro
أَجَعَلَ الْآلِهَةَ إِلَٰهًا وَاحِدًا ۖ إِنَّ هَٰذَا لَشَيْءٌ عُجَابٌ

Se o maa so awon orisa di Olohun Okan soso ti A oo maa josin fun ni? Dajudaju eyi ma ni nnkan iyanu
وَانْطَلَقَ الْمَلَأُ مِنْهُمْ أَنِ امْشُوا وَاصْبِرُوا عَلَىٰ آلِهَتِكُمْ ۖ إِنَّ هَٰذَا لَشَيْءٌ يُرَادُ

Awon asiwaju ninu won si lo (kaakiri lati wi fun awon omoleyin won) pe: "E maa ba (iborisa) lo, ki e si duro sinsin ti awon orisa yin. Dajudaju eyi (jije okan soso Allahu) ni nnkan ti won n gba lero (lati fi pa awon orisa yin run)
مَا سَمِعْنَا بِهَٰذَا فِي الْمِلَّةِ الْآخِرَةِ إِنْ هَٰذَا إِلَّا اخْتِلَاقٌ

Awa ko gbo eyi ninu esin ikeyin (iyen, esin kristieniti) . Eyi ko je kini kan bi ko se adapa iro
أَأُنْزِلَ عَلَيْهِ الذِّكْرُ مِنْ بَيْنِنَا ۚ بَلْ هُمْ فِي شَكٍّ مِنْ ذِكْرِي ۖ بَلْ لَمَّا يَذُوقُوا عَذَابِ

Se Won so Iranti kale fun un laaarin wa ni?" Rara, won wa ninu iyemeji nipa Iranti Mi (ti Mo sokale ni). Rara, won ko ti i to iya Mi wo ni
أَمْ عِنْدَهُمْ خَزَائِنُ رَحْمَةِ رَبِّكَ الْعَزِيزِ الْوَهَّابِ

Tabi (se) awon ni won ni awon apoti oro Oluwa re, Alagbara, Olore
أَمْ لَهُمْ مُلْكُ السَّمَاوَاتِ وَالْأَرْضِ وَمَا بَيْنَهُمَا ۖ فَلْيَرْتَقُوا فِي الْأَسْبَابِ

Tabi tiwon ni ijoba awon sanmo ati ile ati ohun ti n be laaarin mejeeji? Ti o ba ri bee, ki won wa awon ona lati fi gunke wa (ba Wa)
Load More