Surah Yunus Translated in Yoruba
أَكَانَ لِلنَّاسِ عَجَبًا أَنْ أَوْحَيْنَا إِلَىٰ رَجُلٍ مِنْهُمْ أَنْ أَنْذِرِ النَّاسَ وَبَشِّرِ الَّذِينَ آمَنُوا أَنَّ لَهُمْ قَدَمَ صِدْقٍ عِنْدَ رَبِّهِمْ ۗ قَالَ الْكَافِرُونَ إِنَّ هَٰذَا لَسَاحِرٌ مُبِينٌ
Se o je kayefi fun awon eniyan pe A fi imisi ranse si arakunrin kan ninu won, pe: “Se ikilo fun awon eniyan, ki o si fun awon t’o gbagbo ni iro idunnu pe esan rere (ise ti won se) siwaju ti wa ni odo Oluwa won.”? Awon alaigbagbo wi pe: “Dajudaju opidan ponnbele ma ni (Anabi) yii.”
إِنَّ رَبَّكُمُ اللَّهُ الَّذِي خَلَقَ السَّمَاوَاتِ وَالْأَرْضَ فِي سِتَّةِ أَيَّامٍ ثُمَّ اسْتَوَىٰ عَلَى الْعَرْشِ ۖ يُدَبِّرُ الْأَمْرَ ۖ مَا مِنْ شَفِيعٍ إِلَّا مِنْ بَعْدِ إِذْنِهِ ۚ ذَٰلِكُمُ اللَّهُ رَبُّكُمْ فَاعْبُدُوهُ ۚ أَفَلَا تَذَكَّرُونَ
Dajudaju Oluwa yin ni Allahu, Eni ti O seda awon sanmo ati ile fun ojo mefa. Leyin naa, O gunwa si ori Ite-ola. O n seto oro (eda). Ko si olusipe kan afi leyin iyonda Re. Iyen ni Allahu, Oluwa yin. Nitori naa, e josin fun Un. Se e o nii lo iranti ni
إِلَيْهِ مَرْجِعُكُمْ جَمِيعًا ۖ وَعْدَ اللَّهِ حَقًّا ۚ إِنَّهُ يَبْدَأُ الْخَلْقَ ثُمَّ يُعِيدُهُ لِيَجْزِيَ الَّذِينَ آمَنُوا وَعَمِلُوا الصَّالِحَاتِ بِالْقِسْطِ ۚ وَالَّذِينَ كَفَرُوا لَهُمْ شَرَابٌ مِنْ حَمِيمٍ وَعَذَابٌ أَلِيمٌ بِمَا كَانُوا يَكْفُرُونَ
Odo Re ni ibupadasi gbogbo yin. (O je) adehun Allahu ni ododo. Dajudaju Oun l’O n pile dida eda. Leyin naa, O maa da a pada (sodo Re) nitori ki O le fi deede san esan fun awon t’o gbagbo ni ododo, ti won si se ise rere. Awon t’o si sai gbagbo, ohun mimu gbigbona ati iya eleta-elero n be fun won nitori pe won sai gbagbo
هُوَ الَّذِي جَعَلَ الشَّمْسَ ضِيَاءً وَالْقَمَرَ نُورًا وَقَدَّرَهُ مَنَازِلَ لِتَعْلَمُوا عَدَدَ السِّنِينَ وَالْحِسَابَ ۚ مَا خَلَقَ اللَّهُ ذَٰلِكَ إِلَّا بِالْحَقِّ ۚ يُفَصِّلُ الْآيَاتِ لِقَوْمٍ يَعْلَمُونَ
(Allahu) Oun ni Eni ti O se oorun ni itansan. (O se) osupa ni imole. O si diwon (irisi) re sinu awon ibuso nitori ki e le mo onka awon odun ati isiro (ojo). Allahu ko da iyen bi ko se pelu ododo. O n salaye awon ayah fun ijo t’o nimo
إِنَّ فِي اخْتِلَافِ اللَّيْلِ وَالنَّهَارِ وَمَا خَلَقَ اللَّهُ فِي السَّمَاوَاتِ وَالْأَرْضِ لَآيَاتٍ لِقَوْمٍ يَتَّقُونَ
Dajudaju awon ami wa ninu itelentele ati iyato oru ati osan ati ohun ti Allahu da sinu awon sanmo ati ile; (ami wa ninu won) fun ijo t’o n beru (Allahu)
إِنَّ الَّذِينَ لَا يَرْجُونَ لِقَاءَنَا وَرَضُوا بِالْحَيَاةِ الدُّنْيَا وَاطْمَأَنُّوا بِهَا وَالَّذِينَ هُمْ عَنْ آيَاتِنَا غَافِلُونَ
Dajudaju awon ti ko reti ipade Wa (ni orun), ti won yonu si isemi aye, ti okan won si bale dodo si (isemi aye yii) ati awon afonu-fora nipa awon ayah Wa
أُولَٰئِكَ مَأْوَاهُمُ النَّارُ بِمَا كَانُوا يَكْسِبُونَ
awon wonyen, ibugbe won ni Ina nitori ohun ti won n se nise
إِنَّ الَّذِينَ آمَنُوا وَعَمِلُوا الصَّالِحَاتِ يَهْدِيهِمْ رَبُّهُمْ بِإِيمَانِهِمْ ۖ تَجْرِي مِنْ تَحْتِهِمُ الْأَنْهَارُ فِي جَنَّاتِ النَّعِيمِ
Dajudaju awon t’o gbagbo ni ododo, ti won si se awon ise rere, Oluwa won yoo fi igbagbo ododo won to won sona. Awon odo yo si maa san ni isale odo won ninu Ogba Idera
دَعْوَاهُمْ فِيهَا سُبْحَانَكَ اللَّهُمَّ وَتَحِيَّتُهُمْ فِيهَا سَلَامٌ ۚ وَآخِرُ دَعْوَاهُمْ أَنِ الْحَمْدُ لِلَّهِ رَبِّ الْعَالَمِينَ
Adua won ninu re ni “mimo ni fun O, Allahu”. Ikini won ninu re ni “alaafia”. Ipari adua won si ni pe “gbogbo ope n je ti Allahu, Oluwa gbogbo eda”
Load More