Quran Apps in many lanuages:

Surah Yusuf Translated in Yoruba

الر ۚ تِلْكَ آيَاتُ الْكِتَابِ الْمُبِينِ
’Alif lam ro. Iwonyi ni awon ayah Tira t’o yanju oro eda
إِنَّا أَنْزَلْنَاهُ قُرْآنًا عَرَبِيًّا لَعَلَّكُمْ تَعْقِلُونَ
Dajudaju Awa so o kale ni nnkan kike ni ede Larubawa nitori ki e le se laakaye
نَحْنُ نَقُصُّ عَلَيْكَ أَحْسَنَ الْقَصَصِ بِمَا أَوْحَيْنَا إِلَيْكَ هَٰذَا الْقُرْآنَ وَإِنْ كُنْتَ مِنْ قَبْلِهِ لَمِنَ الْغَافِلِينَ
Awa n so itan t’o dara julo fun o pelu ohun ti A fi ranse si o (ninu imisi) al-Ƙur’an yii, bi o tile je pe siwaju imisi naa iwo wa lara awon ti ko nimo (nipa re)
إِذْ قَالَ يُوسُفُ لِأَبِيهِ يَا أَبَتِ إِنِّي رَأَيْتُ أَحَدَ عَشَرَ كَوْكَبًا وَالشَّمْسَ وَالْقَمَرَ رَأَيْتُهُمْ لِي سَاجِدِينَ
(Ranti) nigba ti (Anabi) Yusuf so fun baba re pe: “Baba mi, dajudaju emi (lalaa) ri awon irawo mokanla, oorun ati osupa. Mo ri won ti won fori kanle fun mi.”
قَالَ يَا بُنَيَّ لَا تَقْصُصْ رُؤْيَاكَ عَلَىٰ إِخْوَتِكَ فَيَكِيدُوا لَكَ كَيْدًا ۖ إِنَّ الشَّيْطَانَ لِلْإِنْسَانِ عَدُوٌّ مُبِينٌ
O so pe: "Omo mi, ma se ro ala re fun awon obakan re nitori ki won ma baa dete si o. Dajudaju Esu ni ota ponnbele fun eniyan
وَكَذَٰلِكَ يَجْتَبِيكَ رَبُّكَ وَيُعَلِّمُكَ مِنْ تَأْوِيلِ الْأَحَادِيثِ وَيُتِمُّ نِعْمَتَهُ عَلَيْكَ وَعَلَىٰ آلِ يَعْقُوبَ كَمَا أَتَمَّهَا عَلَىٰ أَبَوَيْكَ مِنْ قَبْلُ إِبْرَاهِيمَ وَإِسْحَاقَ ۚ إِنَّ رَبَّكَ عَلِيمٌ حَكِيمٌ
Bayen ni Oluwa re yoo se sa o lesa. O maa fi itumo ala mo o. O si maa pe idera Re fun iwo ati awon ebi Ya‘ƙub, gege bi O se pe e siwaju fun awon baba re mejeeji, (Anabi) ’Ibrohim ati ’Ishaƙ. Dajudaju Oluwa re ni Onimo, Ologbon
لَقَدْ كَانَ فِي يُوسُفَ وَإِخْوَتِهِ آيَاتٌ لِلسَّائِلِينَ
Dajudaju awon ami (ariwoye) n be fun awon onibeeere nipa (itan Anabi) Yusuf ati awon obakan re
إِذْ قَالُوا لَيُوسُفُ وَأَخُوهُ أَحَبُّ إِلَىٰ أَبِينَا مِنَّا وَنَحْنُ عُصْبَةٌ إِنَّ أَبَانَا لَفِي ضَلَالٍ مُبِينٍ
(Ranti) nigba ti won so pe: "Dajudaju Yusuf ati omo-iya re ni baba wa nifee si ju awa. Opo eniyan si ni awa. Dajudaju baba wa ma ti wa ninu asise ponnbele
اقْتُلُوا يُوسُفَ أَوِ اطْرَحُوهُ أَرْضًا يَخْلُ لَكُمْ وَجْهُ أَبِيكُمْ وَتَكُونُوا مِنْ بَعْدِهِ قَوْمًا صَالِحِينَ
E pa Yusuf tabi ki e lo gbe e junu si ile (miiran) nitori ki baba yin le roju gbo tiyin. E si maa di eniyan rere leyin re
قَالَ قَائِلٌ مِنْهُمْ لَا تَقْتُلُوا يُوسُفَ وَأَلْقُوهُ فِي غَيَابَتِ الْجُبِّ يَلْتَقِطْهُ بَعْضُ السَّيَّارَةِ إِنْ كُنْتُمْ فَاعِلِينَ
Onsoro kan ninu won so pe: "E ma se pa Yusuf. Ti o ba je pe e sa fe wa nnkan se (si oro re), e gbe e ju sinu isaleesale kannga nitori ki apa kan ninu awon onirin-ajo le baa he e lo
Load More